bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
1 Samuel 11
1 Samuel 11
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 12 →
1
NAHAṢI ara Ammoni si goke wá, o si do ti Jabeṣi-Gileadi: gbogbo ọkunrin Jabeṣi si wi fun Nahaṣi, pe, Ba wa da majẹmu, awa o si ma sìn ọ.
2
Nahaṣi ara Ammoni na si da wọn lohùn pe, Nipa bayi li emi o fi ba nyin da majẹmu, nipa yiyọ gbogbo oju ọtun nyin kuro, emi o si fi i ṣe ẹlẹyà li oju gbogbo Israeli.
3
Awọn agba Jabeṣi si wi fun u pe, Fun wa li ayè ni ijọ meje, awa o si ran onṣẹ si gbogbo agbegbe Israeli bi ko ba si ẹniti yio gbà wa, awa o si jade tọ ọ wá.
4
Awọn iranṣẹ na si wá si Gibea ti Saulu, nwọn rohìn na li eti awọn enia: gbogbo enia na si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun.
5
Si kiye si i, Saulu bọ̀ wá ile lẹhin ọwọ́ malu lati papa wá; Saulu si wipe, Ẽṣe awọn enia ti nwọn fi nsọkun? Nwọn si sọ ọ̀rọ awọn ọkunrin Jabeṣi fun u.
6
Ẹmi Ọlọrun si bà le Saulu nigbati o gbọ́ ọ̀rọ wọnni, inu rẹ̀ si ru pipọ.
7
O si mu malu meji, o rẹ́ wọn wẹwẹ, o si ran wọn si gbogbo agbegbe Israeli nipa ọwọ́ awọn onṣẹ na, wipe, Ẹnikẹni ti o wu ki o ṣe ti ko ba tọ Saulu ati Samueli lẹhin, bẹ̃ gẹgẹ li a o ṣe si malu rẹ̀. Ibẹ̀ru Oluwa si mu awọn enia na, nwọn si jade bi enia kanṣoṣo.
8
O si kà wọn ni Beseki, awọn ọmọ Israeli si jẹ ọkẹ mẹ̃dogun enia; awọn ọkunrin Juda si jẹ ẹgbã mẹ̃dogun.
9
Nwọn si wi fun awọn iranṣẹ na ti o ti wá pe, Bayi ni ki ẹ wi fun awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi; Li ọla, lakoko igbati õrùn ba mu, ẹnyin o ni iranlọwọ. Awọn onṣẹ na wá, nwọn rò o fun awọn ọkunrin Jabeṣi; nwọn si yọ̀.
10
Nitorina awọn ọkunrin Jabeṣi wi pe, lọla awa o jade tọ nyin wá, ẹnyin o si fi wa, ṣe bi gbogbo eyi ti o tọ loju nyin.
11
O si ri bẹ̃ lọla na, Saulu si ya awọn enia na si ẹgbẹ mẹta; nwọn si wá ãrin ogun na ni iṣọ owurọ̀, nwọn si pa awọn ara Ammoni titi o fi di igba imoru ọjọ: o si ṣe awọn iyoku fọnka, tobẹ̃ ti meji wọn ko kù ni ibi kan.
12
Awọn enia na si wi fun Samueli, pe, Tani wipe, Saulu yio ha jọba lori wa? mu awọn ọkunrin na wá, a o si pa wọn.
13
Saulu si wi pe, a kì yio pa ẹnikẹni loni yi; nitoripe loni li Oluwa ṣiṣẹ igbala ni Israeli.
14
Nigbana ni Samueli wi fun awọn enia na pe, Wá, ki a lọ si Gilgali, ki a le tun ijọba na ṣe nibẹ.
15
Gbogbo enia na si lọ si Gilgali; nibẹ ni nwọn gbe fi Saulu jọba niwaju Oluwa ni Gilgali: nibẹ ni nwọn gbe ru ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa; nibẹ ni Saulu ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli si yọ ayọ̀ nlanla.
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 12 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
Recommended Reading
Commentary
1 Samuel Commentaries
→
Devotional
1 Samuel Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ) Study Bible
→