bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
1 Samuel 13
1 Samuel 13
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 14 →
1
SAULU jọba li ọdun kan; nigbati o si jọba ọdun meji lori Israeli,
2
Saulu si yan ẹgbẹ̃dogun ọmọkunrin fun ara rẹ̀ ni Israeli; ẹgbã si wà lọdọ Saulu ni Mikmaṣi ati li oke-nla Beteli; ẹgbẹrun si wà lọdọ Jonatani ni Gibea ti Benjamini; o si rán awọn enia ti o kù olukuluku si agọ rẹ̀.
3
Jonatani si pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini ti o wà ninu ile olodi ni Geba, awọn Filistini si gbọ́. Saulu fun ipè yi gbogbo ilẹ na ka, wipe, Jẹ ki awọn Heberu gbọ́.
4
Gbogbo Israeli si gbọ́ pe Saulu pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini, Israeli si di irira fun awọn Filistini. Awọn enia na si pejọ lẹhin Saulu lati lọ si Gilgali.
5
Awọn Filistini kó ara wọn jọ lati ba Israeli jà, ẹgbã-mẹ̃dogun kẹkẹ, ẹgbãta ọkunrin ẹlẹṣin, enia si pọ̀ bi yanrin leti okun; nwọn si goke, nwọn do ni Mikmaṣi ni iha ila õrun Bet-Afeni.
6
Awọn ọkunrin Israeli si ri pe, nwọn wà ninu ipọnju (nitoripe awọn enia na wà ninu ìhamọ) nigbana ni awọn enia na fi ara pamọ ninu iho, ati ninu panti, ninu apata, ni ibi giga, ati ninu kanga gbigbẹ.
7
Omiran ninu awọn Heberu goke odo Jordani si ilẹ Gadi ati Gileadi. Bi o ṣe ti Saulu, on wà ni Gilgali sibẹ, gbogbo enia na si nwariri lẹhin rẹ̀.
8
O si duro ni ijọ meje, de akoko ti Samueli dá fun u; ṣugbọn Samueli kò wá si Gilgali, awọn enia si tuka kuro li ọdọ rẹ̀.
9
Saulu si wipe, Mu ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na fun mi wá, o si ru ẹbọ sisun na.
10
O si ṣe, bi o ti ṣe ẹbọ ọrẹ ati ẹbọ sisun wọnni pari, si kiye si i, Samueli de; Saulu si jade lati lọ pade rẹ̀, ki o le ki i.
11
Samueli si bi i pe, Kini iwọ ṣe yi? Saulu si dahùn pe, Nitoriti emi ri pe awọn enia na ntuka kuro lọdọ mi, iwọ kò si wá li akoko ọjọ ti o dá, awọn Filistini si ko ara wọn jọ ni Mikmaṣi.
12
Nitorina li emi ṣe wipe, Nisisiyi li awọn Filistini yio sọkalẹ tọ mi wá si Gilgali, bẹ̃li emi ko iti tù Oluwa loju; emi si tì ara mi si i, mo si ru ẹbọ sisun na.
13
Samueli si wi fun Saulu pe, iwọ kò hu iwà ọlọgbọ́n: iwọ ko pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ, ti on ti pa li aṣẹ fun ọ: nitori nisisiyi li Oluwa iba fi idi ijọba rẹ kalẹ̀ lori Israeli lailai.
14
Ṣugbọn nisisiyi ijọba rẹ kì yio duro pẹ: Oluwa ti wá fun ara rẹ̀ ọkunrin ti o wù u li ọkàn rẹ̀, Oluwa paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rẹ̀, nitoripe iwọ kò pa aṣẹ ti Oluwa fi fun ọ mọ.
15
Samueli si dide, o si lọ lati Gilgali si Gibea ti Benjamini. Saulu si ka awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, o jẹ iwọ̀n ẹgbẹta ọkunrin.
16
Saulu, ati Jonatani ọmọ rẹ̀, ati awọn enia na ti o wà lọdọ wọn si joko ni Gibea ti Benjamini, ṣugbọn awọn Filistini do ni Mikmaṣi.
17
Ẹgbẹ awọn onisùmọ̀mi mẹta jade ni ibudo awọn Filistini: ẹgbẹ kan gbà ọ̀na ti Ofra, si ilẹ Ṣuali.
18
Ẹgbẹ kan si gba ọ̀na Bet-horoni: ati ẹgbẹ kan si gbà ọ̀na agbegbe nì ti o kọju si afonifoji Seboimu ti o wà ni iha iju.
19
Kò si alagbẹdẹ ninu gbogbo ilẹ Israeli: nitori ti awọn Filistini wipe, Ki awọn Heberu ki o má ba rọ idà tabi ọ̀kọ.
20
Ṣugbọn gbogbo Israeli a ma tọ̀ awọn Filistini lọ, olukuluku lati pọ́n doje rẹ̀, ati ọ̀kọ rẹ̀, ati ãke rẹ̀, ati ọ̀ṣọ rẹ̀.
21
Ṣugbọn nwọn ni ayùn fun ọ̀ṣọ, ati fun ọ̀kọ, ati fun òya-irin ti ilẹ, ati fun ãke, ati lati pọn irin ọpa oluṣọ malu.
22
Bẹ̃li o si ṣe li ọjọ ijà, ti a kò ri idà, tabi ọ̀kọ lọwọ ẹnikẹni ninu awọn enia ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani; lọdọ Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ li a ri.
23
Awọn ọmọ-ogun Filistini jade lọ si ikọja Mikmaṣi.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31