bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
1 Samuel 29
1 Samuel 29
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 30 →
1
AWỌN Filistini si ko gbogbo ogun wọn jọ si Afeki: Israeli si do ni ibi isun omi ti o wà ni Jesreeli.
2
Awọn ijoye Filistini si kọja li ọrọrun ati li ẹgbẹgbẹrun; Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pẹlu Akiṣi si kẹhin.
3
Awọn ijoye Filistini si bere wipe, Kini awọn Heberu nṣe nihinyi? Akiṣi si wi fun awọn ijoye Filistini pe, Dafidi kọ yi, iranṣẹ Saulu ọba Israeli, ti o wà lọdọ mi lati ọjọ wọnyi tabi lati ọdun wọnyi, emi ko iti ri iṣiṣe kan li ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ ti o ti de ọdọ mi titi di oni yi.
4
Awọn ijoye Filistini si binu si i; awọn ijoye Filistini si wi fun u pe, jẹ ki ọkunrin yi pada ki o si lọ si ipò rẹ̀ ti o fi fun u, ki o má si jẹ ki o ba wa sọkalẹ lọ si ogun, ki o má ba jasi ọta fun wa li ogun; Kini on o fi ba oluwa rẹ̀ laja, ori awọn enia wọnyi kọ?
5
Ṣe eyi ni Dafidi ti nwọn tori rẹ̀ gberin ara wọn ninu ijo wipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun rẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbãrun tirẹ̀?
6
Akiṣi si pe Dafidi, o si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, iwọ jẹ olõtọ ati ẹni ìwa rere loju mi, ni alọ rẹ ati abọ̀ rẹ pẹlu mi li ogun; nitoripe emi ko iti ri buburu kan lọwọ rẹ lati ọjọ ti iwọ ti tọ̀ mi wá, titi o fi di oni yi: ṣugbọn loju awọn ijoye iwọ kò ṣe ẹni ti o tọ́.
7
Njẹ yipada ki o si ma lọ li alafia, ki iwọ ki o má ba ṣe ibanujẹ fun awọn Filistini.
8
Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Kili emi ṣe? kini iwọ si ri lọwọ iranṣẹ rẹ lati ọjọ ti emi ti gbe niwaju rẹ titi di oni yi, ti emi kì yio fi lọ ba awọn ọta ọba ja?
9
Akiṣi si dahun o si wi fun Dafidi pe, Emi mọ̀ pe iwọ ṣe ẹni-rere loju mi, bi angeli Ọlọrun: ṣugbọn awọn ijoye Filistini wi pe, On kì yio ba wa lọ si ogun.
10
Njẹ, nisisiyi dide li owurọ pẹlu awọn iranṣẹ oluwa rẹ ti o ba ọ wá: ki ẹ si dide li owurọ nigbati ilẹ ba mọ́, ki ẹ si ma lọ.
11
Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si dide li owurọ lati pada lọ si ilẹ awọn Filistini. Awọn Filistini si goke lọ si Jesreeli.
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 30 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31