bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
1 Samuel 27
1 Samuel 27
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 28 →
1
DAFIDI si wi li ọkàn ara rẹ̀ pe, njẹ ni ijọ kan l'emi o ti ọwọ́ Saulu ṣegbe, ko si si ohun ti o yẹ mi jù ki emi ki o yara sa asala lọ si ilẹ awọn Filistini: yio su Saulu lati ma tun wá mi kiri ni gbogbo agbegbe Israeli: emi a si bọ li ọwọ́ rẹ̀.
2
Dafidi si dide, o si rekọja, on ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti o mbẹ lọdọ rẹ̀ si Akiṣi, ọmọ Maoki, ọba Gati.
3
Dafidi si ba Akiṣi joko ni Gati, on, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, olukuluku wọn ti on ti ara ile rẹ̀; Dafidi pẹlu awọn aya rẹ̀ mejeji, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili ara Karmeli aya Nabali.
4
A si sọ fun Saulu pe, Dafidi sa lọ si Gati: on ko si tun wá a kiri mọ.
5
Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Bi o ba jẹ pe emi ri ore ọfẹ loju rẹ, jẹ ki wọn ki o fun mi ni ibi kan ninu awọn ileto wọnni; emi o ma gbe ibẹ: ẽṣe ti iranṣẹ rẹ yio si ma ba ọ gbe ni ilu ọba?
6
Akiṣi si fi Siklagi fun u ni ijọ na; nitorina ni Siklagi fi di ti awọn ọba Juda titi o fi di oni yi.
7
Iye ọjọ ti Dafidi fi joko ni ilu awọn Filistini si jẹ ọdun kan ati oṣu mẹrin.
8
Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ, nwọn si gbe ogun ti awọn ara Geṣuri, ati awọn ara Gesra, ati awọn ara Amaleki: awọn wọnyi li o si ti ngbe ni ilẹ, na nigba atijọ, bi iwọ ti nlọ si Ṣuri titi o fi de ilẹ Egipti.
9
Dafidi si kọlu ilẹ na, ko si fi ọkunrin tabi obinrin silẹ lãye, o si ko agùtan, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ, ati aṣọ, o si yipada o si tọ Akisi wá.
10
Akiṣi si bi i pe, Nibo li ẹnyin gbe rìn si loni? Dafidi si dahun pe, Siha gusu ti Juda ni, ati siha gusun ti Jerameeli, ati siha gusu ti awọn ara Keni:
11
Dafidi kò si da ọkunrin tabi obinrin si lãye, lati mu ihin wá si Gati, wipe, Ki nwọn ki o má ba sọ ọ̀rọ wa nibẹ, pe, Bayi ni Dafidi ṣe, ati bẹ̃ni iṣe rẹ̀ yio si ri ni gbogbo ọjọ ti yio fi joko ni ilu awọn Filistini.
12
Akiṣi si gba ti Dafidi gbọ́, wipe, On ti mu ki Israeli ati awọn enia rẹ̀ korira rẹ̀ patapata, yio si jẹ iranṣẹ mi titi lai.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31