bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
2 Chronicles 10
2 Chronicles 10
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 11 →
1
REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu: nitori gbogbo Israeli wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba.
2
O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọmọ Nebati gbọ́, on si wà ni Egipti nibiti o ti salọ kuro niwaju Solomoni ọba, ni Jeroboamu pada ti Egipti wá.
3
Nwọn si ranṣẹ pè e. Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo Israeli wá, nwọn si ba Rehoboamu sọ̀rọ, wipe,
4
Baba rẹ mu ki àjaga wa ki o wuwo: njẹ nisisiyi iwọ ṣẹkù kuro ninu ìsin baba rẹ ti o nira, ati àjaga wuwo rẹ̀ ti o fi bọ̀ wa lọrùn, awa o si ma sìn ọ.
5
On si wi fun wọn pe, Ẹ tun pada tọ̀ mi wá lẹhin ijọ mẹta. Awọn enia na si lọ.
6
Rehoboamu ọba si ba awọn àgbagba ti o ti nduro niwaju Solomoni baba rẹ̀; nigbati o wà lãye dá imọran, wipe, imọran kili ẹnyin dá lati da awọn enia yi lohùn?
7
Nwọn si ba a sọ̀rọ pe, bi iwọ ba ṣe ire fun enia yi, ti iwọ ba ṣe ohun ti o wù wọn, ti o ba si sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ nigbagbogbo.
8
Ṣugbọn o kọ̀ imọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti o dàgba pẹlu rẹ̀ damọran, ti o duro niwaju rẹ̀.
9
On si wi fun wọn pe, Imọran kili ẹnyin dá, ki awa ki o le da awọn enia yi lohùn, ti o ba mi sọ̀rọ, wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi bọ̀ wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ?
10
Awọn ipẹrẹ ti a tọ́ pẹlu rẹ̀ si sọ fun u wipe, Bayi ni iwọ o da awọn enia na li ohùn ti o sọ fun ọ, wipe, Baba rẹ mu àjaga wa di wuwo, ṣugbọn iwọ ṣe e ki o fẹrẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o wi fun wọn, Ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ.
11
Njẹ nisisiyi baba mi ti fi àjaga wuwo bọ̀ nyin lọrùn, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin.
12
Jeroboamu ati gbogbo awọn enia si tọ̀ Rehoboamu wá ni ijọ kẹta gẹgẹ bi ọba ti dá, wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta.
13
Nigbana ni ọba da wọn li ohùn akọ; Rehoboamu ọba si kọ̀ imọran awọn àgbagba silẹ.
14
O si da wọn li ohùn gẹgẹ bi imọran awọn ipẹrẹ, wipe, Baba mi mu àjaga nyin ki o wuwo, ṣugbọn emi o fi kún u; baba mi ti fi paṣan nà nyin, ṣugbọn emi o fi akẽke nà nyin.
15
Bẹ̃ni ọba kò si fetisi ti awọn enia na: nitori ṣiṣẹ ọ̀ran na lati ọwọ Ọlọrun wá ni, ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti o sọ nipasẹ Ahijah, ara Ṣilo fun Jeroboamu, ọmọ Nebati.
16
Nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kọ̀ lati fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba lohùn, wipe, Ipin kili a ni ninu Dafidi? awa kò si ni ini kan ninu ọmọ Jesse: Israeli, olukuluku sinu agọ rẹ̀: nisisiyi Dafidi, mã bojuto ile rẹ. Bẹ̃ni gbogbo Israeli lọ sinu agọ wọn,
17
Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli ti ngbe ilu Juda wọnni, Rehoboamu jọba lori wọn.
18
Nigbana ni Rehoboamu ọba ran Hadoramu ti iṣe olori iṣẹ-irú; awọn ọmọ Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Ṣugbọn Rehoboamu ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀ lati salọ si Jerusalemu.
19
Bẹ̃ni Israeli si ya kuro lọdọ ile Dafidi titi o fi di oni yi.
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36