bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
2 Chronicles 22
2 Chronicles 22
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 21
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 23 →
1
AWỌN olugbe Jerusalemu, si fi Ahasiah, ọmọ rẹ̀ abikẹhin, jọba ni ipò rẹ̀: nitori awọn ẹgbẹ́ ogun, ti o ba awọn ara Arabia wá ibudo, ti pa gbogbo awọn ẹgbọn. Bẹ̃ni Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, jọba.
2
Ẹni ọdun mejilelogun ni Ahasiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun kan ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Ataliah, ọmọbinrin Omri.
3
On pẹlu rìn li ọ̀na Ahabu: nitori iya rẹ̀ ni igbimọ̀ rẹ̀ lati ṣe buburu.
4
O si ṣe buburu loju Oluwa bi ile Ahabu: nitori awọn wọnyi li o nṣe igbimọ̀ rẹ̀ lẹhin ikú baba rẹ̀ si iparun rẹ̀.
5
O tẹle imọ̀ran wọn pẹlu; o si ba Jehoramu, ọmọ Ahabu, ọba Israeli, lọ iba Hasaeli, ọba Siria jagun, ni Ramoti-Gileadi: awọn ara Siria si ṣá Jehoramu li ọgbẹ.
6
O si pada lọ iwora ni Jesreeli, nitori ọgbẹ ti a ṣá a ni Rama, nigbati o fi ba Hasaeli, ọba Siria jà. Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, si sọ̀kalẹ lọ iwò Jehoramu, ọmọ Ahabu, ni Jesreeli, nitoriti o ṣaisan.
7
Iparun Ahasiah lati ọwọ Ọlọrun wá ni, nipa wiwá sọdọ Jehoramu: nigbati o si de, o si ba Jehoramu jade tọ̀ Jehu, ọmọ Nimṣi, ẹniti Oluwa fi ororo yàn lati ké ile Ahabu kuro.
8
O si ṣe nigbati Jehu nmu idajọ ṣẹ sori ile Ahabu, o si ri awọn ijoye Juda, ati awọn ọmọ awọn arakunrin Ahasiah, ti nṣe iranṣẹ fun Ahasiah, o si pa wọn.
9
O si wá Ahasiah: nwọn si mu u, (on sa ti fi ara pamọ́ ni Samaria,) nwọn si mu u tọ̀ Jehu wá: nigbati nwọn si pa a tan, nwọn sìn i: nitori ti nwọn wipe, ọmọ Jehoṣafati ni, ẹniti o wá Oluwa tọkàntọkan rẹ̀. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ni ile Ahasiah ti o yẹ fun ijọba.
10
Ṣugbọn nigbati Ataliah, iya Ahasiah, ri pe ọmọ on kú, o dide o si run gbogbo iru ọmọ ijọba ile Judah.
11
Ṣugbọn Jehoṣabeati, ọmọbinrin ọba, mu Joaṣi, ọmọ Ahasiah, o ji i kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa, o fi on ati olutọ rẹ̀ sinu yẹwu Ibusùn. Bẹ̃ni Jehoṣabeati, ọmọbinrin Jehoramu ọba, aya Jehoiada, alufa, (nitori arabinrin Ahasiah li on) o pa a mọ́ kuro lọdọ Ataliah ki o má ba pa a.
12
O si wà pẹlu wọn ni pipamọ́ ninu ile Ọlọrun li ọdun mẹfa: Ataliah si jọba lori ilẹ na.
← Chapter 21
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 23 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36