bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
2 Chronicles 14
2 Chronicles 14
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 15 →
1
Bẹ̃ni Abijah sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Asa ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Li ọjọ rẹ̀, ilẹ na wà li alafia li ọdun mẹwa.
2
Asa si ṣe eyi ti o dara, ti o si tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.
3
Nitori ti o mu pẹpẹ awọn ajeji oriṣa kuro, ati ibi giga wọnni, o si wó awọn ere palẹ, o si bẹ ere-oriṣa wọn lulẹ:
4
O si paṣẹ fun Juda lati ma wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, ati lati ma pa aṣẹ ati ofin rẹ̀ mọ́.
5
O si mu ibi giga wọnni ati ọwọ̀n-õrun wọnni kuro lati inu gbogbo ilu Juda: ijọba na si wà li alafia niwaju rẹ̀.
6
O si kọ́ ilu olodi wọnni ni Juda, nitoriti ilẹ na ni isimi, on kò si ni ogun li ọdun wọnni; nitori Oluwa ti fun wọn ni isimi.
7
O si sọ fun Juda pe, Ẹ jẹ ki a kọ́ ilu wọnni, ki a si mọdi yi wọn ka, ati ile-iṣọ, ilẹkun ati ọpa-idabu, nigbati ilẹ na si wà niwaju wa, nitori ti awa ti wá Oluwa Ọlọrun wa, awa ti wá a, on si ti fun wa ni isimi yikakiri. Bẹ̃ni nwọn kọ́ wọn, nwọn si ṣe rere.
8
Asa si ni ogun ti ngbé asà ati ọ̀kọ, ọkẹ mẹdogun lati inu Juda wá, ati lati inu Benjamini wá, ọkẹ mẹrinla ti ngbé apata ati ti nfa ọrun: gbogbo wọnyi si ni akọni ogun.
9
Sera, ara Etiopia, si jade si wọn, pẹlu ãdọta ọkẹ enia, ati ọ̃dunrun kẹkẹ́; nwọn wá si Mareṣa.
10
Asa si jade tọ̀ ọ, nwọn si tẹ ogun li afonifoji Sefata lẹba Mareṣa.
11
Asa si ke pe Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, Oluwa! lọdọ rẹ bakanna ni fun ọ lati ràn alagbara enia lọwọ, tabi ẹniti kò li agbara: ràn wa lọwọ, Oluwa Ọlọrun wa; nitori ti awa gbẹkẹ le ọ, li orukọ rẹ li awa ntọ ọ̀pọlọpọ yi lọ, Oluwa, iwọ li Ọlọrun wa; máṣe jẹ ki enia ki o bori rẹ,
12
Bẹ̃li Oluwa kọlù awọn ara Etiopia niwaju Asa, ati niwaju Juda: awọn ara Etiopia si sa.
13
Ati Asa ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ lepa wọn de Gerari: a si bi awọn ara Etiopia ṣubu ti ẹnikan kò tun wà li ãye; nitori ti a ṣẹ́ wọn niwaju Oluwa ati niwaju ogun rẹ̀; nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ikogun lọ.
14
Nwọn si kọlu gbogbo ilu yikakiri Gerari: nitori ti ẹ̀ru Oluwa bà wọn, nwọn si kó gbogbo ilu na, nitori ikógun pọ̀ rekọja ninu wọn.
15
Nwọn si kọlù awọn agbo-ẹran-ọsin, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ agutan ati ibakasiẹ lọ, nwọn si pada wá si Jerusalemu.
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36