bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
2 Chronicles 12
2 Chronicles 12
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 13 →
1
O si ṣe, nigbati Rehoboamu ti fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ ti o si ti mu ara rẹ̀ le, o kọ̀ ofin Oluwa silẹ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀.
2
O si ṣe ni ọdun karun Rehoboamu ọba, ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, gòke wá si Jerusalemu, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa.
3
Pẹlu ẹgbẹfa kẹkẹ́, ati ọkẹ́ mẹta ẹlẹṣin: awọn enia ti o ba a ti Egipti wá kò niye; awọn ara Libia, awọn ara Sukki, ati awọn ara Etiopia.
4
O si kọ́ awọn ilu olodi ti iṣe ti Juda, o si wá si Jerusalemu.
5
Nigbana ni Ṣemaiah, woli, tọ̀ Rehoboamu wá, ati awọn ijoye Juda, ti o kojọ pọ̀ si Jerusalemu nitori Ṣiṣaki, o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi, enyin ti kọ̀ mi silẹ, nitorina li emi si ṣe fi nyin silẹ si ọwọ Ṣiṣaki.
6
Nigbana li awọn ijoye Israeli ati ọba rẹ̀ ara wọn silẹ; nwọn si wipe: Oluwa li olododo!
7
Nigbati Oluwa ri pe nwọn rẹ̀ ara wọn silẹ, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Ṣemaiah wá, wipe, Nwọn ti rẹ̀ ara wọn silẹ; nitorina emi kì o run wọn, ṣugbọn emi o fun wọn ni igbala diẹ: a kì yio dà ibinu mi sori Jerusalemu nipa ọwọ Ṣiṣaki.
8
Ṣugbọn nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ̀: ki nwọn ki o le mọ̀ ìsin mi, ati ìsin ijọba ilẹ wọnni.
9
Bẹ̃ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, goke wá si Jerusalemu, o si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; o kó gbogbo rẹ̀: o kó awọn asà wura lọ pẹlu ti Solomoni ti ṣe.
10
Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn le ọwọ olori ẹṣọ ti ntọju ọ̀na ile ọba.
11
O si ṣe, nigbakugba ti ọba ba si wọ̀ ile Oluwa lọ, awọn ẹṣọ a de, nwọn a si kó wọn wá, nwọn a si kó wọn pada sinu iyara ẹṣọ.
12
Nigbati o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ibinu Oluwa yipada kuro lọdọ rẹ̀, ti kò fi run u patapata: ni Juda pẹlu, ohun rere si mbẹ.
13
Bẹ̃ni Rehoboamu ọba mu ara rẹ̀ le ni Jerusalemu, o si jọba: nitori Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹtadinlogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni.
14
O si ṣe buburu, nitori ti kò mura ọkàn rẹ̀ lati wá Oluwa.
15
Njẹ iṣe Rehoboamu, ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kò ha kọ wọn sinu iwe Ṣemaiah, woli, ati ti Iddo, ariran, nipa iwe itan idile? Ọtẹ si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu nigbagbogbo.
16
Rehoboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi: Abijah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36