bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Ezekiel 12
Ezekiel 12
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 13 →
1
Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2
Ọmọ enia, iwọ ngbe ãrin ọlọ̀tẹ ile, ti nwọn ni oju lati ri, ti kò si ri; nwọn ni eti lati gbọ́, nwọn kò si gbọ́: nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.
3
Nitorina, iwọ ọmọ enia, mura nkan kikolọ, ki o si kó lọ li oju wọn li ọsan; ki o si kó lati ipò rẹ lọ si ibomiran li oju wọn; o le ṣe pe nwọn o ronu, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọ̀tẹ ile.
4
Ki o si mu nkan rẹ jade li ọsan li oju wọn, bi nkan kikolọ; ki o si jade lọ li aṣalẹ li oju wọn, bi awọn ti nlọ si igbekùn.
5
Da ogiri lu loju wọn, ki o si kó jade nibẹ.
6
Li oju wọn ni ki o rù u le ejika rẹ, ki o si rù u lọ ni wiriwiri alẹ, ki o si bo oju rẹ, ki o má ba ri ilẹ; nitori mo ti gbe ọ kalẹ fun àmi si ile Israeli.
7
Mo si ṣe bi a ti paṣẹ fun mi: mo mu nkan mi jade li ọsan, bi nkan fun igbekùn, mo si fi ọwọ́ mi dá ogiri lu li aṣalẹ; mo gbe e jade ni wiriwiri alẹ, mo si rù u le ejika mi loju wọn.
8
Li owurọ ọ̀rọ Oluwa si ti tọ̀ mi wá, wipe,
9
Ọmọ enia, ile Israeli, ọlọ̀tẹ ile nì kò ti wi fun ọ pe, kini iwọ nṣe?
10
Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹrù yi hàn fun awọn ọmọ-alade ni Jerusalemu, ati gbogbo ile Israeli ti o wà lãrin wọn.
11
Wipe, emi ni àmi nyin, gẹgẹ bi mo ti ṣe, bẹ̃ni a o si ṣe si wọn: nwọn o ko kuro, nwọn o si lọ si igbekùn.
12
Ọmọ-alade ti o wà larin wọn yio si rẹrù lori ejika rẹ̀ ni wiriwiri alẹ, yio si jade lọ; nwọn o si dá ogiri lu lati kó jade nibẹ; yio si bo oju rẹ̀, ki o má ba fi oju rẹ̀ ri ilẹ.
13
Awọ̀n mi ni emi o si tẹ́ le e lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi: emi o si mu u wá si Babiloni, si ilẹ awọn ara Kaldea; kì yio si ri i, bẹ̃ni yio kú nibẹ.
14
Gbogbo awọn ti o yi i ka lati ràn a lọwọ, ati gbogbo ọwọ-ogun rẹ̀, ni emi o tuká si gbogbo afẹ̃fẹ, emi o si yọ idà le wọn.
15
Nwọn o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa, nigbati mo ba tú wọn ka lãrin awọn orilẹ-ède; ti mo ba si fọ́n wọn ká ilẹ pupọ.
16
Ṣugbọn emi o kù diẹ ninu wọn silẹ lọwọ idà, lọwọ iyàn, ati lọwọ ajakálẹ arùn; ki nwọn le sọ gbogbo ohun ẽri wọn lãrin awọn keferi, nibiti nwọn ba de; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
17
Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
18
Ọmọ enia, fi ìgbọnriri jẹ onjẹ rẹ, si fi ìwariri ati ikiyesara mu omi rẹ;
19
Ki o si sọ fun awọn enia ilẹ na pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn ara Jerusalemu, niti ilẹ Israeli; nwọn o fi ikiyesara jẹ onjẹ wọn, nwọn o si fi iyanu mu omi wọn, ki ilẹ rẹ̀ ki o le di ahoro kuro ninu gbogbo ohun ti o wà ninu rẹ̀, nitori ìwa-ipá gbogbo awọn ti ngbe ibẹ̀.
20
Awọn ilu ti a ngbe yio di ofo, ilẹ na yio si di ahoro; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
21
Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
22
Ọmọ enia, owe wo li ẹnyin ni, ni ilẹ Israeli pe, A fà ọjọ gùn, gbogbo iran di asan?
23
Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o jẹ ki owe yi dẹkun, nwọn kì yio si pa a li owe ni Israeli mọ; ṣugbọn wi fun wọn pe, Ọjọ kù si dẹ̀dẹ; ati imuṣẹ gbogbo iran.
24
Nitori kì yio si iran asan mọ, kì yio si si afọṣẹ ti npọnni ninu ile Israeli.
25
Nitori emi li Oluwa: emi o sọ̀rọ, ọ̀rọ ti emi o sọ yio si ṣẹ, a kì yio fà a gùn mọ; nitori li ọjọ nyin, Ọlọtẹ ile, li emi o sọ ọ̀rọ na, emi o si ṣe e, ni Oluwa Ọlọrun wi.
26
Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,
27
Ọmọ enia, kiyesi i, awọn ara ile Israeli wipe, Iran ti o ri, fun ọjọ pupọ ti mbọ̀ ni, o si sọ asọtẹlẹ akoko ti o jina rere.
28
Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Kò si ọkan ninu ọ̀rọ mi ti a o fà gùn mọ, ṣugbọn ọ̀rọ ti mo ti sọ yio ṣẹ, ni Oluwa wi.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48