bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Ezekiel 35
Ezekiel 35
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 34
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 36 →
1
Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2
Ọmọ enia, kọ oju rẹ si oke Seiri, ki o si sọtẹlẹ si i.
3
Ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Kiyesi i, iwọ oke Seiri, emi dojukọ ọ, emi o nà ọwọ́ mi si ọ, emi o si sọ ọ di ahoro patapata.
4
Emi o sọ awọn ilu rẹ di ahoro, iwọ o si di ahoro, iwọ o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
5
Nitori ti iwọ ti ni irira lailai, iwọ si ti fi awọn ọmọ Israeli le idà lọwọ́, li akoko idãmu wọn, li akoko ti aiṣedẽde wọn de opin.
6
Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi o pèse rẹ silẹ fun ẹ̀jẹ, ẹ̀jẹ yio si lepa rẹ: bi iwọ kò ti korira ẹ̀jẹ nì, ẹ̀jẹ yio lepa rẹ.
7
Bayi li emi o sọ oke Seiri di ahoro patapata, emi o si ké ẹniti nkọja lọ ati ẹniti npadà bọ̀ kuro ninu rẹ̀.
8
Emi o si fi awọn okú rẹ̀ kún awọn oke rẹ̀; ni oke kékèké rẹ, ati ni afonifoji rẹ, ati ni gbogbo odò rẹ li awọn ti a fi idà pa yio ṣubu si.
9
Emi o sọ ọ di ahoro lailai, awọn ilu rẹ kì yio si padà bọ̀: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
10
Nitoriti iwọ ti wipe, Awọn orilẹ-ède mejeji yi, ati awọn ilẹ mejeji yi yio jẹ́ ti emi, awa o si ni i; nigbati o ṣepe Oluwa wà nibẹ:
11
Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi emi o tilẹ ṣe gẹgẹ bi ibinu rẹ, ati gẹgẹ bi ilara rẹ ti iwọ ti lò lati inu irira rẹ si wọn; emi o si sọ ara mi di mimọ̀ lãrin wọn, nigbati emi ba ti da ọ li ẹjọ.
12
Iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa, ati pe emi ti gbọ́ ọ̀rọ buburu rẹ, ti iwọ ti sọ si oke Israeli, wipe, A sọ wọn di ahoro, a fi wọn fun wa lati run.
13
Bayi li ẹnyin ti fi ẹnu nyin buná si mi, ẹ si ti sọ ọ̀rọ nyin di pupọ si mi: emi ti gbọ́.
14
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi pe, Nigbati gbogbo aiye nyọ̀, emi o sọ ọ di ahoro.
15
Gẹgẹ bi iwọ ti yọ̀ si ini ile Israeli, nitori ti o di ahoro, bẹ̃li emi o ṣe si ọ; iwọ o di ahoro, iwọ oke Seiri ati gbogbo Idumea, ani gbogbo rẹ̀: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
← Chapter 34
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 36 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48