bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Ezekiel 29
Ezekiel 29
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 30 →
1
LI ọdun kẹwa, li oṣù kẹwa, li ọjọ kejila oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
2
Ọmọ enia, kọ oju rẹ si Farao ọba Egipti, si sọtẹlẹ si i, ati si gbogbo Egipti:
3
Sọ̀rọ, ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi doju kọ ọ; Farao ọba Egipti, dragoni nla ti o dubulẹ li ãrin awọn odò rẹ̀, eyiti o ti wipe, Ti emi li odò mi, emi li o si ti wà a fun ara mi.
4
Ṣugbọn emi o fi ìwọ kọ́ ọ li ẹ̀rẹkẹ́, emi o si jẹ ki ẹja odò rẹ ki o lẹ mọ́ ipẹ́ rẹ, emi o si mu ọ kuro li ãrin odò rẹ, ati gbogbo ẹja odò rẹ yio lẹ mọ́ ipẹ́ rẹ.
5
Emi o si sọ ọ nù si aginjù, iwọ ati gbogbo ẹja odò rẹ: iwọ o ṣubu ni gbangba oko: a kì yio si kó ọ jọ, bẹ̃li a kì yio si ṣà ọ jọ: emi ti fi ọ ṣe onjẹ fun awọn ẹranko igbẹ́, ati fun awọn ẹiyẹ oju ọrun.
6
Gbogbo awọn olugbé Egipti yio mọ̀ pe emi li Oluwa, nitori nwọn ti jẹ́ ọpá ìye fun ile Israeli.
7
Nigbati nwọn di ọ lọwọ mu, iwọ fọ́, o si ya gbogbo èjiká wọn: nigbati nwọn si fi ara tì ọ, iwọ ṣẹ́, o si mu gbogbo ẹgbẹ́ wọn gbọ̀n.
8
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Kiyesi i, emi o mu idà kan wá sori rẹ, ti yio ké enia ati ẹranko kuro ninu rẹ.
9
Ilẹ Egipti yio si di aginjù yio si di ahoro; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa: nitori ti o ti wipe, Odò na temi ni, emi li o si ti wà a.
10
Nitorina, kiyesi i, emi dojukọ ọ, mo si dojukọ odò rẹ, emi o si sọ ilẹ Egipti di ahoro patapata, lati Migdoli lọ de Siene ati titi de ẹkùn Etiopia.
11
Ẹsẹ enia kì yio kọja li ãrin rẹ̀, bẹ̃ni ẹsẹ ẹrankẹran kì yio kọja li ãrin rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio tẹ̀ ẹ dó li ogoji ọdun.
12
Emi o si sọ ilẹ Egipti di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ati ilu rẹ̀ yio si di ahoro li ãrin awọn ilu ti o di ahoro li ogoji ọdun: emi o si tú awọn ara Egipti ká sãrin gbogbo orilẹ-ède, emi o si tú wọn ká sãrin gbogbo ilẹ.
13
Ṣugbọn bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Lẹhin ogoji ọdun li emi o ko awọn ara Egipti jọ lati ọdọ awọn enia nibiti a ti tú wọn ká si:
14
Emi o si tun mu igbèkun Egipti pada bọ̀, emi o si mu wọn pada si ilẹ Patrosi, si ilẹ ibí wọn, nwọn o si wà nibẹ bi ijọba ti a rẹ̀ silẹ.
15
Yio si jẹ ijọba ti o rẹ̀lẹ jù ninu awọn ijọba; bẹ̃ni kì yio si gbe ara rẹ̀ ga mọ́ sori awọn orilẹ-ède: nitori emi o dín wọn kù, ti nwọn kì yio fi ṣe olori awọn orilẹ-ède mọ́.
16
Kì yio si jẹ igbẹkẹle fun ile Israeli mọ́, ti o mu aiṣedẽde wọn wá si iranti, nigbati nwọn o ba wò wọn: ṣugbọn nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.
17
O si ṣe li ọdun kẹtadilọgbọ̀n, li oṣù ikini, li ọjọ ikini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
18
Ọmọ enia, Nebukadresari ọba Babiloni mu ki ogun rẹ̀ sìn irú nla si Tire: gbogbo ori pá, ati gbogbo èjiká bó: sibẹsibẹ on, ati awọn ogun rẹ̀, kò ri owo ọ̀ya gbà, lati Tire fun irú ti o ti sìn si i:
19
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o fi ilẹ Egipti fun Nebukadresari ọba Babiloni; yio si kó awọn ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, ati ikógun rẹ̀, ati ijẹ rẹ̀; yio si jẹ owo ọ̀ya fun awọn ogun rẹ̀.
20
Mo ti fi ilẹ Egipti fun u, fun irú ti o sìn si i, nitoriti nwọn ṣiṣẹ́ fun mi, li Oluwa Ọlọrun wi.
21
Li ọjọ na li emi o mu ki iwọ Israeli rú jade, emi o si fun ọ ni iṣínu li ãrin wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 30 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48