bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Ezekiel 28
Ezekiel 28
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 29 →
1
Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
2
Ọmọ enia, sọ fun ọmọ-alade Tire pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti ọkàn rẹ gbe soke, ati ti iwọ si wipe, Ọlọrun li emi, emi joko ni ibujoko Ọlọrun, larin okun; ṣugbọn enia ni iwọ, iwọ kì isi ṣe Ọlọrun, bi o tilẹ gbe ọkàn rẹ soke bi ọkàn Ọlọrun.
3
Wo o, iwọ sa gbọn ju Danieli lọ; kò si si ohun ikọ̀kọ ti o le fi ara sin fun ọ.
4
Ọgbọ́n rẹ ati oye rẹ li o fi ni ọrọ̀, o si ti ni wura ati fadáka sinu iṣura rẹ:
5
Nipa ọgbọ́n rẹ nla ati nipa òwo rẹ li o ti fi sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ, ọkàn rẹ si gbe soke nitori ọrọ̀ rẹ.
6
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti o ti ṣe ọkàn rẹ bi ọkàn Ọlọrun;
7
Kiyesi i, nitorina emi o mu alejo wá ba ọ, ẹlẹ̀ru ninu awọn orilẹ-ède: nwọn o si fà idà wọn yọ si ẹwà ọgbọ́n rẹ, nwọn o si bà didán rẹ jẹ.
8
Nwọn o mu ọ sọkalẹ wá sinu ihò, iwọ o si kú ikú awọn ti a pa li ãrin okun.
9
Iwọ ha le sọ sibẹ niwaju ẹni ti npa ọ, pe, Emi li Ọlọrun? ṣugbọn enia ni iwọ, o kì yio si jẹ Ọlọrun, lọwọ ẹniti npa ọ.
10
Iwọ o kú ikú awọn alaikọlà lọwọ awọn alejo: nitori emi li o ti sọ ọ, li Oluwa Ọlọrun wi.
11
Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,
12
Ọmọ enia, pohùnréré sori ọba Tire, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ fi edidi dí iye na, o kún fun ọgbọ́n, o si pé li ẹwà.
13
Iwọ ti wà ni Edeni ọgbà Ọlọrun; oniruru okuta iyebiye ni ibora rẹ, sardiu, topasi, ati diamondi, berili, oniki, ati jasperi, safire, emeraldi, ati karbunkili, ati wura: iṣẹ ìlu rẹ ati ti fère rẹ li a pèse ninu rẹ li ọjọ ti a dá ọ.
14
Iwọ ni kerubu ti a nà ti o si bò; emi si ti gbe ọ kalẹ: iwọ wà lori oke mimọ́ Ọlọrun; iwọ ti rìn soke rìn sodò lãrin okuta iná.
15
Iwọ pé li ọnà rẹ lati ọjọ ti a ti dá ọ, titi a fi ri aiṣedẽde ninu rẹ.
16
Nitori ọ̀pọlọpọ òwo rẹ, nwọn ti fi iwà-ipa kún ãrin rẹ, iwọ si ti ṣẹ̀: nitorina li emi o ṣe sọ ọ nù bi ohun ailọ̀wọ kuro li oke Ọlọrun: emi o si pa ọ run, iwọ kerubu ti o bò, kuro lãrin okuta iná.
17
Ọkàn rẹ gbe soke nitori ẹwà rẹ, o ti bà ọgbọ́n rẹ jẹ nitori dídan rẹ; emi o bì ọ lulẹ, emi o gbe ọ kalẹ niwaju awọn ọba, ki nwọn ba le wò ọ.
18
Iwọ ti bà ibi mimọ́ rẹ jẹ nipa ọ̀pọlọpọ aiṣedẽde rẹ, nipa aiṣedẽde òwo rẹ; nitorina emi o mu iná jade lati ãrin rẹ wá, yio jó ọ run, emi o si sọ ọ di ẽru lori ilẹ loju gbogbo awọn ti o wò ọ:
19
Gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ lãrin awọn orilẹ-ède li ẹnu o yà si ọ: iwọ o jẹ ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́ lailai.
20
Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
21
Ọmọ enia, gbé oju rẹ si Sidoni, ki o si sọtẹlẹ si i,
22
Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Sa wò o, Emi doju kọ ọ, iwọ Sidoni; a o si ṣe mi logo li ãrin rẹ, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o bá ti mu idajọ mi ṣẹ ninu rẹ̀, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu rẹ̀.
23
Emi o si rán àjakálẹ àrun sinu rẹ̀, ati ẹjẹ ni igboro rẹ̀; a o si fi idà pa awọn si a ṣá li ọgbẹ li ãrin rẹ̀ lori rẹ̀ nihà gbogbo; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
24
Kì yio si si ẹgún ti ngún ni fun ile Israeli mọ́, tabi ẹgún bibani ninu jẹ́ ti gbogbo awọn ti o yi wọn ká, ti o si ṣãtá wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.
25
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Nigbati emi o bá ti kó ile Israeli jọ kuro lãrin awọn orilẹ-ède ti a tú wọn ká si, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu wọn loju awọn keferi, nigbana ni nwọn o gbé ilẹ wọn ti mo ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi.
26
Nwọn o si ma gbé inu rẹ̀ ni ibalẹ-aiya, nwọn o si kọ́ ile, nwọn o si gbìn ọgbà àjara; nitõtọ, nwọn o wà ni ibalẹ-aiya, nigbati emi bá ti mu idajọ mi ṣẹ si ara awọn ti ngàn wọn yi wọn kakiri, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn.
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 29 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48