bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Genesis 18
Genesis 18
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 19 →
1
OLUWA si farahàn a ni igbo Mamre: on si joko li ẹnu-ọ̀na agọ́ ni imõru ọjọ́:
2
O si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, ọkunrin mẹta duro li ẹba ọdọ rẹ̀: nigbati o si ri wọn, o sure lati ẹnu-ọ̀na agọ́ lọ ipade wọn, o si tẹriba silẹ.
3
O si wipe, OLUWA mi, njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, emi bẹ̀ ọ, máṣe kọja lọ kuro lọdọ ọmọ-ọdọ rẹ:
4
Jẹ ki a mu omi diẹ wá nisisiyi, ki ẹnyin ki o si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ki ẹnyin ki o si simi labẹ igi:
5
Emi o si mu onjẹ diẹ wá, ki ẹnyin si fi ọkàn nyin balẹ; lẹhin eyini ki ẹnyin ma kọja lọ: njẹ nitorina li ẹnyin ṣe tọ̀ ọmọ-ọdọ nyin wá. Nwọn si wipe, Ṣe bẹ̃ bi iwọ ti wi.
6
Abrahamu si yara tọ̀ Sara lọ ninu agọ́, o wipe, Yara mu òṣuwọn iyẹfun daradara mẹta, ki o pò o, ki o si dín akara.
7
Abrahamu si sure lọ sinu agbo, o si mu ẹgbọrọ-malu kan ti o rọ̀ ti o dara, o fi fun ọmọkunrin kan; on si yara lati sè e.
8
O si mu orí-amọ́, ati wàra, ati ẹgbọrọ malu ti o sè, o si gbé e kalẹ niwaju wọn: on si duro tì wọn li abẹ igi na, nwọn si jẹ ẹ.
9
Nwọn si bi i pe, nibo ni Sara aya rẹ wà? o si wipe, wò o ninu agọ́.
10
O si wipe, Emi o si tun pada tọ̀ ọ wá nitõtọ ni iwoyi amọ́dun; si kiyesi i, Sara aya rẹ yio li ọmọkunrin kan. Sara si gbọ́ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ti o wà lẹhin ọkunrin na.
11
Njẹ Abrahamu on Sara gbó, nwọn si pọ̀ li ọjọ́; o si dẹkun ati ma ri fun Sara bi ìwa obinrin.
12
Nitorina Sara rẹrin ninu ara rẹ̀ wipe, Lẹhin igbati mo di ogbologbo tan, emi o ha li ayọ̀, ti oluwa mi si di ogbologbo pẹlu?
13
OLUWA si wi fun Abrahamu pe, Nitori kini Sara ṣe nrẹrin wipe, Emi o ha bímọ nitõtọ, ẹniti o ti gbó tán?
14
Ohun kan ha ṣoro fun OLUWA? li akoko ti a dá emi o pada tọ̀ ọ wa, ni iwoyi amọ́dun, Sara yio si li ọmọkunrin kan.
15
Sara si sẹ, wipe, Emi kò rẹrin; nitoriti o bẹ̀ru. On si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn iwọ rẹrin.
16
Awọn ọkunrin na si dide kuro nibẹ̀, nwọn kọju sihà Sodomu: Abrahamu si ba wọn lọ lati sìn wọn de ọ̀na.
17
OLUWA si wipe, Emi o ha pa ohun ti emi o ṣe mọ́ fun Abrahamu:
18
Nitori pe, Abrahamu yio sa di orilẹ-ède nla ati alagbara, ati gbogbo orilẹ-ède aiye li a o bukun fun nipasẹ rẹ̀?
19
Nitoriti mo mọ̀ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ara ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọ̀na OLUWA mọ́ lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u.
20
OLUWA si wipe, Nitori ti igbe Sodomu on Gomorra pọ̀, ati nitori ti ẹ̀ṣẹ wọn pàpọju.
21
Emi o sọkalẹ lọ nisisiyi, ki nri bi nwọn tilẹ ṣe, gẹgẹ bi okikí igbe rẹ̀, ti o de ọdọ mi; bi bẹ si kọ, emi o mọ̀.
22
Awọn ọkunrin na si yi oju wọn pada kuro nibẹ̀, nwọn si lọ si Sodomu: ṣugbọn Abrahamu duro sibẹ̀ niwaju OLUWA.
23
Abrahamu si sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Iwọ o ha run olododo pẹlu enia buburu?
24
Bọya ãdọta olododo yio wà ninu ilu na: iwọ o ha run u, iwọ ki yio ha dá ibẹ̀ na si nitori ãdọta olododo ti o wà ninu rẹ̀?
25
O ha dára, ti iwọ o fi ṣe bi irú eyi, lati run olododo pẹlu enia buburu; ti awọn olododo yio fi dabi awọn enia buburu, o ha dára: Onidajọ gbogbo aiye ki yio ha ṣe eyi ti o tọ́?
26
OLUWA si wipe, Bi mo ba ri ãdọta olododo ninu ilu Sodomu, njẹ emi o dá gbogbo ibẹ̀ si nitori wọn.
27
Abrahamu si dahùn o si wipe, Wò o nisisiyi, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ, emi ẹniti iṣe erupẹ ati ẽru.
28
Bọya marun a dín ninu ãdọta olododo na: iwọ o ha run gbogbo ilu na nitori marun? On si wipe, Bi mo ba ri marunlelogoji nibẹ̀, emi ki yio run u.
29
O si tun sọ fun u ẹ̀wẹ, o ni, Bọya, a o ri ogoji nibẹ̀, On si wipe, Emi ki o run u nitori ogoji.
30
O si tun wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, emi o si ma wi: bọya a o ri ọgbọ̀n nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u bi mo ba ri ọgbọ̀n nibẹ̀.
31
O si wipe, Wò o na, emi ti dawọle e lati ba OLUWA sọ̀rọ: bọya a o ri ogun nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori ogun.
32
O si wipe, Jọ̃, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, ẹ̃kanṣoṣo yi li emi o si wi mọ. Bọya a o ri mẹwa nibẹ̀. On si wipe, Emi ki yio run u nitori mẹwa.
33
OLUWA si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna bi o ti ba Abrahamu sọ̀rọ tan; Abrahamu si pada lọ si ibujoko rẹ̀.
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 19 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50