bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Genesis 25
Genesis 25
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 26 →
1
ABRAHAMU si tun fẹ́ aya kan, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Ketura.
2
O si bí Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaku, ati Ṣua fun u.
3
Jokṣani si bí Ṣeba, ati Dedani. Awọn ọmọ Dedani si ni Aṣurimu, ati Letuṣimu, ati Leumimu.
4
Ati awọn ọmọ Midiani; Efa, ati Eferi, ati Hanoku, ati Abida, ati Eldaa. Gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Ketura.
5
Abrahamu si fi gbogbo ohun ti o ni fun Isaaki.
6
Ṣugbọn awọn ọmọ àle ti Abrahamu ni, Abrahamu bùn wọn li ẹ̀bun, o si rán wọn lọ kuro lọdọ Isaaki, ọmọ rẹ̀, nigbati o wà lãye, si ìha ìla-õrùn, si ilẹ ìla-õrùn.
7
Iwọnyi si li ọjọ́ ọdún aiye Abrahamu ti o wà, arun dí lọgọsan ọdún.
8
Abrahamu si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú li ogbologbo, arugbo, o kún fun ọjọ́; a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀.
9
Awọn ọmọ rẹ̀, Isaaki ati Iṣmaeli si sin i ni ihò Makpela, li oko Efroni, ọmọ Sohari enia Hitti, ti o wà niwaju Mamre;
10
Oko ti Abrahamu rà lọwọ awọn ọmọ Heti: nibẹ̀ li a gbé sin Abrahamu, ati Sara, aya rẹ̀.
11
O si ṣe lẹhin ikú Abrahamu li Ọlọrun bukún fun Isaaki, ọmọ rẹ̀; Isaaki si joko leti kanga Lahai-roi.
12
Iwọnyi si ni iran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, ti Hagari, ara Egipti, ọmọbinrin ọdọ Sara bí fun Abrahamu:
13
Iwọnyi si li orukọ awọn ọmọkunrin Iṣmaeli, nipa orukọ wọn, ni iran idile wọn: akọ́bi Iṣmaeli, Nebajotu; ati Kedari, ati Adbeeli, ati Mibsamu,
14
Ati Miṣma, ati Duma, ati Masa;
15
Hadari, ati Tema, Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema:
16
Awọn wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli, iwọnyi si li orukọ wọn, li ori-ori ilu wọn, li ori-ori ile odi wọn; ijoye mejila li orilẹ-ède wọn.
17
Iwọnyi si li ọdún aiye Iṣmaeli, ẹtadilogoje ọdún: o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú; a si kó o jọ pọ̀ pẹlu awọn enia rẹ.
18
Nwọn si tẹ̀dó lati Hafila lọ titi o fi de Ṣuri, ti o wà niwaju Egipti, bi iwọ ti nlọ sìha Assiria: o si kú niwaju awọn arakonrin rẹ̀ gbogbo.
19
Iwọnyi si ni iran Isaaki, ọmọ Abrahamu: Abrahamu bí Isaaki:
20
Isaaki si jẹ ẹni ogoji ọdún, nigbati o mu Rebeka, ọmọbinrin Betueli, ara Siria ti Padan-aramu, arabinrin Labani ara Siria, li aya.
21
Isaaki si bẹ̀ OLUWA fun aya rẹ̀, nitoriti o yàgan: OLUWA si gbà ẹ̀bẹ rẹ̀, Rebeka, aya rẹ̀, si loyun.
22
Awọn ọmọ si njàgudu ninu rẹ̀: o si wipe, bi o ba ṣe pe bẹ̃ni yio ri, ẽṣe ti mo fi ri bayi? O si lọ bère lọdọ OLUWA.
23
OLUWA si wi fun u pe, orilẹ-ède meji ni mbẹ ninu rẹ, irú enia meji ni yio yà lati inu rẹ: awọn enia kan yio le jù ekeji lọ; ẹgbọ́n ni yio si ma sìn aburo.
24
Nigbati ọjọ́ rẹ̀ ti yio bí si pé, si kiyesi i, ibeji li o wà ninu rẹ̀.
25
Akọ́bi si jade wá, o pupa, ara rẹ̀ gbogbo ri bí aṣọ onirun; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Esau.
26
Ati lẹhin eyini li arakunrin rẹ̀ jade wá, ọwọ́ rẹ̀ si dì gigĩsẹ Esau mu; a si sọ orukọ rẹ̀ ni Jakobu: Isaaki si jẹ ẹni ọgọta ọdún nigbati Rebeka bí wọn.
27
Awọn ọmọdekunrin na si dàgba: Esau si ṣe ọlọgbọ́n ọdẹ, ara oko; Jakobu si ṣe ọbọrọ́ enia, a ma gbé inu agọ́.
28
Isaaki si fẹ́ Esau, nitori ti o njẹ ninu ẹran-ọdẹ rẹ̀: ṣugbọn Rebeka fẹ́ Jakobu.
29
Jakobu si pa ìpẹtẹ: Esau si ti inu igbẹ́ dé, o si rẹ̀ ẹ:
30
Esau si wi fun Jakobu pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ìpẹtẹ rẹ pupa nì bọ́ mi; nitori ti o rẹ̀ mi: nitori na li a ṣe npè orukọ rẹ̀ ni Edomu.
31
Jakobu si wipe, Tà ogún-ibí rẹ fun mi loni.
32
Esau si wipe, Sa wò o na, emi ni nkú lọ yi: ore kini ogún-ibí yi yio si ṣe fun mi?
33
Jakobu si wipe, Bura fun mi loni; o si bura fun u: o si tà ogún-ibí rẹ̀ fun Jakobu.
34
Nigbana ni Jakobu fi àkara ati ìpẹtẹ lentile fun Esau; o si jẹ, o si mu, o si dide, o si ba tirẹ̀ lọ: bayi ni Esau gàn ogún-ibí rẹ̀.
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 26 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50