bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Genesis 48
Genesis 48
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 47
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 49 →
1
O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi ni ẹnikan wi fun Josefu pe, Kiyesi i, ara baba rẹ kò dá: o si mú awọn ọmọ rẹ̀ mejeji, Manasse ati Efraimu pẹlu rẹ̀.
2
Ẹnikan si sọ fun Jakobu, o si wipe, Kiyesi i, Josefu ọmọ rẹ tọ̀ ọ wá: Israeli si gbiyanju, o si joko lori akete.
3
Jakobu si wi fun Josefu pe, Ọlọrun Olodumare farahàn mi ni Lusi ni ilẹ Kenaani, o si sure fun mi,
4
O si wi fun mi pe, Kiyesĩ, Emi o mu ọ bisi i, Emi o mu ọ rẹ̀, Emi o si sọ ọ di ọ̀pọlọpọ enia; Emi o si fi ilẹ yi fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iní titi aiye.
5
Njẹ nisisiyi Efraimu ati Manasse, awọn ọmọ rẹ mejeji ti a bí fun ọ ni ilẹ Egipti, ki emi ki o tó tọ̀ ọ wá ni Egipti, ti emi ni nwọn: bi Reubeni on Simeoni, bẹ̃ni nwọn o jẹ́ ti emi.
6
Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ ti iwọ bí lẹhin wọn ni yio ṣe tirẹ, a o si ma pè wọn li orukọ awọn arakunrin wọn ni ilẹ iní wọn.
7
Ati emi, nigbati mo ti Paddani wá, Rakeli kú lọwọ mi ni ilẹ Kenaani li ọ̀na, nigbati o kù diẹ ti a ba fi dé Efrati: emi si sin i nibẹ̀ li ọ̀na Efrati (eyi na ni Betlehemu).
8
Israeli si wò awọn ọmọ Josefu, o si bère pe, Tani wọnyi?
9
Josefu wi fun baba rẹ̀ pe, Awọn ọmọ mi ni, ti Ọlọrun fifun mi nihinyi. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mú wọn wá sọdọ mi, emi o si sure fun wọn.
10
Njẹ oju Israeli ṣú baìbai nitori ogbó, kò le riran. On si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀: o si fi ẹnu kò wọn li ẹnu, o si gbá wọn mọra.
11
Israeli si wi fun Josefu pe, Emi kò dába ati ri oju rẹ mọ́: si kiyesi i, Ọlọrun si fi irú-ọmọ rẹ hàn mi pẹlu.
12
Josefu si mú wọn kuro li ẽkun rẹ̀, o si tẹriba, o dà oju rẹ̀ bolẹ.
13
Josefu si mú awọn mejeji, Efraimu li ọwọ́ ọtún rẹ̀ si ọwọ́ òsi Israeli, ati Manasse lọwọ òsi rẹ̀, si ọwọ́ ọtún Israeli, o si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀.
14
Israeli si nà ọwọ́ ọtún rẹ̀, o si fi lé Efraimu ẹniti iṣe aburo li ori, ati ọwọ́ òsi rẹ̀ lé ori Manasse, o mọ̃mọ̀ mu ọwọ́ rẹ̀ lọ bẹ̃: nitori Manasse ni iṣe akọ́bi.
15
O si sure fun Josefu, o si wipe, Ọlọrun, niwaju ẹniti Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi rìn, Ọlọrun na ti o bọ́ mi lati ọjọ́ aiye mi titi di oni,
16
Angeli na ti o dá mi ni ìde kuro ninu ibi gbogbo, ki o gbè awọn ọmọde wọnyi; ki a si pè orukọ mi mọ́ wọn lara, ati orukọ Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi; ki nwọn ki o si di ọ̀pọlọpọ lãrin aiye.
17
Nigbati Josefu ri pe baba rẹ̀ fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ lé Efraimu lori, inu rẹ̀ kò dùn: o si mú baba rẹ̀ li ọwọ́, lati ṣí i kuro li ori Efraimu si ori Manasse.
18
Josefu si wi fun baba rẹ̀ pe, Bẹ̃kọ, baba mi: nitori eyi li akọ́bi; fi ọwọ́ ọtún rẹ lé e li ori.
19
Baba rẹ̀ si kọ̀, o si wipe, Emi mọ̀, ọmọ mi, emi mọ̀: on pẹlu yio di enia, yio si pọ̀ pẹlu: ṣugbọ́n nitõtọ aburo rẹ̀ yio jù u lọ, irú-ọmọ rẹ̀ yio si di ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède.
20
O si sure fun wọn li ọjọ́ na pe, Iwọ ni Israeli o ma fi sure, wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe nyin bi Efraimu on Manasse: bẹ̃li o fi Efraimu ṣaju Manasse.
21
Israeli si wi fun Josefu pe, Wò o, emi kú: ṣugbọn Ọlọrun yio wà pẹlu nyin, yio si tun mú nyin lọ si ilẹ awọn baba nyin.
22
Pẹlupẹlu, emi si fi ilẹ-biri kan fun ọ jù awọn arakunrin rẹ lọ, ti mo fi idà ti on ti ọrun mi gbà lọwọ awọn enia Amori.
← Chapter 47
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 49 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50