bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Genesis 4
Genesis 4
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 5 →
1
ADAMU si mọ̀ Efa aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Kaini, o si wipe, Mo ri ọkunrin kan gbà lọwọ OLUWA.
2
O si bí Abeli arakunrin rẹ̀. Abeli a si ma ṣe oluṣọ-agutan, ṣugbọn Kaini a ma ṣe aroko.
3
O si ṣe, li opin ọjọ́ wọnni ti Kaini mu ọrẹ ninu eso ilẹ fun OLUWA wá.
4
Ati Abeli, on pẹlu mu ninu akọbi ẹran-ọ̀sin ani ninu awọn ti o sanra. OLUWA si fi ojurere wò Abeli ati ọrẹ rẹ̀;
5
Ṣugbọn Kaini ati ọrẹ rẹ̀ ni kò nãni. Kaini si binu gidigidi, oju rẹ̀ si rẹ̀wẹsi.
6
OLUWA si bi Kaini pe, Ẽṣe ti inu fi mbi ọ? ẽ si ti ṣe ti oju rẹ̀ fi rẹ̀wẹsi?
7
Bi iwọ ba ṣe rere, ara ki yio ha yá ọ? bi iwọ kò ba si ṣe rere, ẹ̀ṣẹ ba li ẹnu-ọ̀na, lọdọ rẹ ni ifẹ rẹ̀ yio ma fà si, iwọ o si ma ṣe alakoso rẹ̀.
8
Kaini si ba Abeli arakunrin rẹ̀ sọ̀rọ: o si ṣe, nigbati nwọn wà li oko, Kaini dide si Abeli arakunrin rẹ̀, o si lù u pa.
9
OLUWA si wi fun Kaini pe, Nibo ni Abeli arakunrin rẹ wà? O si wipe, Emi kò mọ̀; emi iṣe olutọju arakunrin mi bi?
10
O si wipe, Kini iwọ ṣe nì? Ohùn ẹ̀jẹ arakunrin rẹ nkigbe pè mi lati inu ilẹ wá.
11
Njẹ nisisiyi a fi ọ ré lori ilẹ, ti o yanu rẹ̀ gbà ẹ̀jẹ arakunrin rẹ lọwọ rẹ.
12
Nigbati iwọ ba ro ilẹ, lati isisiyi lọ, ki yio fi agbara rẹ̀ so eso fun ọ mọ; isansa ati alarinkiri ni iwọ o ma jẹ li aiye.
13
Kaini si wi fun OLUWA pe, ìya ẹ̀ṣẹ mi pọ̀ jù eyiti emi lè rù lọ.
14
Kiye si i, iwọ lé mi jade loni kuro lori ilẹ; emi o si di ẹniti o pamọ kuro loju rẹ; emi o si ma jẹ isansa ati alarinkiri li aiye; yio si ṣe ẹnikẹni ti o ba ri mi yio lù mi pa.
15
OLUWA si wi fun u pe, Nitorina ẹnikẹni ti o ba pa Kaini a o gbẹsan lara rẹ̀ lẹrinmeje. OLUWA si sàmi si Kaini lara, nitori ẹniti o ba ri i ki o má ba pa a.
16
Kaini si jade lọ kuro niwaju OLUWA, o si joko ni ilẹ Nodi, ni ìha ìla-õrùn Edeni.
17
Kaini si mọ̀ aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Enoku: o si tẹ̀ ilu kan dó, o si sọ orukọ ilu na ni Enoku bi orukọ ọmọ rẹ̀ ọkunrin.
18
Fun Enoku li a bí Iradi: Iradi si bí Mehujaeli: Mehujaeli si bí Metuṣaeli: Metuṣaeli si bí Lameki.
19
Lameki si fẹ́ obinrin meji: orukọ ekini ni Ada, ati orukọ ekeji ni Silla.
20
Ada si bí Jabali: on ni baba irú awọn ti o ngbé agọ́, ti nwọn si li ẹran-ọ̀sin.
21
Orukọ arakunrin rẹ̀ ni Jubali: on ni baba irú gbogbo awọn ti nlò dùru ati fère.
22
Ati Silla on pẹlu bí Tubali-kaini, olukọni gbogbo ọlọnà idẹ, ati irin: arabinrin Tubali-kaini ni Naama.
23
Lameki si wi fun awọn aya rẹ̀ pe, Ada on Silla, ẹ gbọ́ ohùn mi; ẹnyin aya Lameki, ẹ fetisi ọ̀rọ mi: nitoriti mo pa ọkunrin kan si ẹ̀dun mi, ati ọdọmọkunrin kan si ipalara mi.
24
Bi a o gbẹsan Kaini lẹrinmeje, njẹ ti Lameki ni ìgba ãdọrin meje.
25
Adamu si tun mọ̀ aya rẹ̀, o si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: o wipe, nitori Ọlọrun yàn irú-ọmọ miran fun mi ni ipò Abeli ti Kaini pa.
26
Ati Seti, on pẹlu li a bí ọmọkunrin kan fun; o si pè orukọ rẹ̀ ni Enoṣi: nigbana li awọn enia bẹ̀rẹ si ikepè orukọ OLUWA.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50