bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Hosea 1
Hosea 1
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 2 →
1
Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Hosea, ọmọ Beeri wá, li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi, ọba Israeli.
2
Ibẹ̀rẹ ọ̀rọ Oluwa si Hosea. Oluwa si wi fun Hosea, pe, Lọ, fẹ́ agbère obinrin kan fun ara rẹ, ati awọn ọmọ agbère; nitori ilẹ yi ti ṣe agbère gidigidi, kuro lẹhin Oluwa.
3
O si lọ o si fẹ́ Gomeri ọmọbinrin Diblaimu; ẹniti o loyún, ti o si bi ọmọkunrin kan fun u.
4
Oluwa si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ ni Jesreeli; nitori niwọ̀n igbà diẹ, emi o bẹ̀ ẹ̀jẹ Jesreeli wò li ara ile Jehu, emi o si mu ki ijọba ile Israeli kasẹ̀.
5
Yio si ṣe li ọjọ na, li emi o ṣẹ́ ọrun Israeli ni afonifojì Jesreeli.
6
O si tún loyún, o si bi ọmọbinrin kan. Ọlọrun si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ li Loruhama: nitori emi kì yio tún ma ṣãnu fun ile Israeli mọ, nitoriti emi o mu wọn kuro.
7
Ṣugbọn emi o ṣãnu fun ile Juda, emi o si fi Oluwa Ọlọrun wọn gbà wọn là, emi kì yio si fi ọrun, tabi idà, tabi ogun, ẹṣin, tabi ẹlẹṣin gbà wọn là.
8
Nigbati o gbà ọmu li ẹnu Loruhama, o si loyún o si bi ọmọkunrin kan.
9
Nigbana ni Ọlọrun wipe, Pè orukọ rẹ̀ ni Loammi; nitori ẹnyin kì iṣe enia mi, emi kì yio si ṣe Ọlọrun nyin.
10
Ṣugbọn iye awọn ọmọ Israeli yio ri bi iyanrìn okun, ti a kò le wọ̀n ti a kò si lè ikà; yio si ṣe, ni ibi ti a gbe ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, ibẹ̀ li a o gbe wi fun wọn pe, Ẹnyin li ọmọ Ọlọrun alãyè.
11
Nigbana ni a o kó awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Israeli jọ̀ pọ̀, nwọn o si yàn olori kan fun ara wọn, nwọn o si jade kuro ni ilẹ na: nitori nla ni ọjọ Jesreeli yio jẹ.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14