bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Hosea 8
Hosea 8
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 9 →
1
FI ipè si ẹnu rẹ. Yio wá bi idì si ile Oluwa, nitori nwọn ti re majẹmu mi kọja, nwọn si ti rú ofin mi.
2
Nwọn o kigbe si mi pe, Ọlọrun mi, awa Israeli mọ̀ ọ.
3
Israeli ti gbe ohunrere sọnù; ọta yio lepa rẹ̀.
4
Nwọn ti fi ọba jẹ, ṣugbọn kì iṣe nipasẹ̀ mi: nwọn ti jẹ olori, ṣugbọn emi kò si mọ̀: fàdakà wọn ati wurà wọn ni nwọn fi ṣe òriṣa fun ara wọn, ki a ba le ké wọn kuro.
5
Ọmọ-malu rẹ ti ta ọ nù, Samaria; ibinu mi rú si wọn: yio ti pẹ to ki nwọn to de ipò ailẹ̀ṣẹ?
6
Nitori lati ọdọ Israeli wá li o ti ri bẹ̃ pẹlu; oniṣọ̀na li o ṣe e; nitorina on kì iṣe Ọlọrun: ṣugbọn ọmọ malu Samaria yio fọ tũtũ.
7
Nitori nwọn ti gbìn ẹfũfũ, nwọn o si ka ãjà: kò ni igi ọka: irúdi kì yio si mu onjẹ wá: bi o ba ṣepe o mu wá, alejò yio gbe e mì.
8
A gbe Israeli mì: nisisiyi ni nwọn o wà lãrin awọn Keferi bi ohun-elò ninu eyiti inu-didùn kò si.
9
Nitori nwọn goke lọ si Assiria, kẹtẹ́kẹtẹ́ igbẹ́ nikan fun ara rẹ̀: Efraimu ti bẹ̀ awọn ọrẹ li ọ̀wẹ.
10
Nitõtọ, bi nwọn tilẹ ti bẹ̀ ọ̀wẹ lãrin awọn orilẹ-ède, nisisiyi li emi o ko wọn jọ, nwọn o si kãnu diẹ fun ẹrù ọba awọn ọmọ-alade.
11
Nitori Efraimu ti tẹ́ pẹpẹ pupọ̀ lati dẹ̀ṣẹ, pẹpẹ yio jẹ ohun atidẹ̀ṣẹ fun u.
12
Mo ti kọwe ohun pupọ̀ ti ofin mi si i, ṣugbọn a kà wọn si bi ohun ajèji.
13
Nwọn rubọ ẹran ninu ẹbọ ẹran mi, nwọn si jẹ ẹ; Oluwa kò tẹwọgbà wọn; nisisiyi ni yio ránti ìwa-buburu wọn, yio si bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò: nwọn o padà lọ si Egipti.
14
Nitori Israeli ti gbagbe Ẹlẹda rẹ̀, o si kọ́ tempili pupọ; Juda si ti sọ ilu olodi di pupọ̀: ṣugbọn emi o rán iná kan si ori awọn ilu rẹ̀, yio si jẹ awọn ãfin rẹ̀ wọnni run.
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14