bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Hosea 10
Hosea 10
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 11 →
1
ÁJARA ofo ni Israeli, o nso eso fun ara rẹ̀; gẹgẹ bi ọ̀pọ eso rẹ̀ li o mu pẹpẹ pọ̀ si i; gẹgẹ bi didara ilẹ rẹ̀ ni nwọn yá ere daradara.
2
Ọkàn wọn dá meji; nisisiyi ni nwọn o jẹbi; on o wó pẹpẹ wọn lulẹ, on o si ba ere wọn jẹ.
3
Nitori nisisiyi ni nwọn o wipe, Awa kò li ọba, nitoriti awa kò bẹ̀ru Oluwa; njẹ kili ọba o ṣe fun wa?
4
Nwọn ti sọ ọ̀rọ, nwọn mbura eke ni didà majẹmu: bayi ni idajọ hù soke bi igi iwọ, ni aporo oko.
5
Nitori awọn ọmọ-malu Bet-afeni, awọn ti ngbe Samaria yio bẹ̀ru: nitori awọn enia ibẹ̀ yio ṣọ̀fọ lori rẹ̀, ati awọn baba-oloriṣà ibẹ̀ ti o yọ̀ lori rẹ̀, nitori ogo rẹ̀, nitori o ti lọ kuro lọdọ rẹ̀.
6
A o si mu u lọ si Assiria pẹlu ẹbùn fun Jarebu ọba: Efraimu yio gbà itiju, oju yio si tì Israeli nitori igbìmọ rẹ̀.
7
Bi o ṣe ti Samaria, a ké ọba rẹ̀ kuro bi ifõfõ loju omi.
8
Ibi giga Afeni pẹlu, ẹ̀ṣẹ Israeli, li a o parun; ẹgún ọ̀gan on oṣuṣu yio hù jade lori pẹpẹ wọn; nwọn o si wi fun awọn oke-nla pe, Bò wa mọlẹ; ati fun awọn oke kékèké pe, Wó lù wa.
9
Lati ọjọ Gibea ni iwọ ti ṣẹ̀, Israeli: nibẹ̀ ni nwọn duro: ogun Gibea si awọn ọmọ ẹ̀ṣẹ kò ha le wọn ba?
10
Ifẹ inu mi ni ki nle nà wọn; a o si gbá awọn enia jọ si wọn, lati di ara wọn si ẹ̀ṣẹ wọn mejeji.
11
Efraimu si dabi ọmọ-malu ti a kọ́, ti o si fẹ́ lati ma tẹ ọkà; ṣugbọn emi rekọja li ori ọrùn rẹ̀ ti o ni ẹwà: emi o mu ki Efraimu gùn ẹṣin; Juda yio tú ilẹ, Jakobu yio si fọ́ ogulùtu rẹ̀.
12
Ẹ furùngbin fun ara nyin li ododo, ẹ ká li ãnu: ẹ tú ilẹ nyin ti a kò ro: nitori o to akokò lati wá Oluwa, titi yio fi de, ti yio si fi rọ̀jo ododo si nyin.
13
Ẹnyin ti tulẹ ìwa-buburu, ẹnyin ti ká aiṣedẽde; ẹnyin ti jẹ eso eke: nitori iwọ gbẹkẹ̀le ọ̀na rẹ, ninu ọ̀pọlọpọ awọn alagbara rẹ.
14
Nitorina li ariwo yio dide ninu awọn enia rẹ, gbogbo awọn odi agbara rẹ li a o si bajẹ, bi Ṣalmani ti ba Bet-abeli jẹ li ọjọ ogun: a fọ́ iya tũtũ lori awọn ọmọ rẹ̀.
15
Bẹ̃ni Beteli yio ṣe si nyin, nitori ìwa-buburu nla nyin; ni kùtukùtu li a o ke ọba Israeli kuro patapata.
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14