bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Hosea 9
Hosea 9
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 10 →
1
MÁṢE yọ̀, Israeli, fun ayọ̀, bi awọn enia miràn: nitori iwọ ti ṣe agbère lọ kuro lọdọ Ọlọrun rẹ, iwọ ti fẹ́ èrè lori ilẹ ipakà gbogbo.
2
Ilẹ ipakà ati ohun ifunti kì yio bọ́ wọn, ọti-waini titun yio si tan ninu rẹ̀.
3
Nwọn kì yio gbe inu ilẹ Oluwa; ṣugbọn Efraimu yio padà si Egipti, nwọn o si jẹ ohun aimọ́ ni Assiria.
4
Nwọn kì yio ta Oluwa li ọrẹ ọti-waini, bẹ̃ni nwọn kì yio mu u ni inu dùn: ẹbọ wọn yio ri fun wọn bi onjẹ awọn ti nṣọ̀fọ; gbogbo awọn ti o jẹ ninu rẹ̀ ni yio di alaimọ́: nitori onjẹ wọn kì yio wá si ile Oluwa fun ọkàn wọn.
5
Kili ẹnyin o ṣe li ọjọ ti o ni irònu, ati li ọjọ àse Oluwa?
6
Nitori, sa wò o, nwọn ti lọ nitori ikogun: Egipti yio kó wọn jọ, Memfisi yio sin wọn: ibi didara fun fadakà wọn li ẹgún-ọ̀gan yio jogun wọn: ẹgún yio wà ninu agọ wọn.
7
Ọjọ ibẹ̀wo de, ọjọ ẹsan de; Israeli yio mọ̀: aṣiwère ni woli na, ẹni ẹmi na nsinwin; nitori ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati irira nla na.
8
Olùṣọ Efraimu wà pẹlu Ọlọrun mi: ṣugbọn okùn pẹyẹpẹyẹ ni woli na li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati irira si ile Ọlọrun rẹ̀.
9
Nwọn ti ba ara wọn jẹ pupọ̀pupọ̀, bi li ọjọ Gibea: nitorina, on o ranti aiṣedẽde wọn, yio bẹ̀ ẹ̀ṣẹ wọn wò.
10
Mo ri Israeli bi eso ajara li aginjù; mo ri awọn baba nyin bi akọpọ́n ninu igi ọpọ̀tọ li akọso rẹ̀: ṣugbọn nwọn tọ̀ Baal-peori lọ, nwọn si yà ara wọn si itiju nì; ohun irira wọn si ri gẹgẹ bi nwọn ti fẹ.
11
Bi o ṣe ti Efraimu, ogo wọn yio fò lọ bi ẹiyẹ, lati ibí, ati lati inu, ati lati iloyun.
12
Bi nwọn tilẹ tọ́ ọmọ wọn dàgba, ṣugbọn emi o gbà wọn li ọwọ wọn, ti kì yio fi kù enia kan; lõtọ, egbe ni fun wọn pẹlu nigbati mo ba kuro lọdọ wọn!
13
Efraimu, bi mo ti ri Tirusi, li a gbìn si ibi daradara: ṣugbọn Efraimu yio bi ọmọ rẹ̀ fun apania.
14
Fun wọn, Oluwa, li ohun ti iwọ o fun wọn. Fun wọn ni iṣẹnu ati ọmú gbigbẹ́.
15
Gbogbo ìwa-buburu wọn mbẹ ni Gilgali; nitori nibẹ̀ ni mo korira wọn; nitori ìwa-buburu iṣe wọn, emi o le wọn kuro ni ile mi, emi kì yio fẹràn wọn mọ́; gbogbo ọmọ-alade wọn ni ọlọ̀tẹ.
16
A lù Efraimu, gbòngbo wọn gbẹ, nwọn kì yio so eso, bi nwọn tilẹ bi ọmọ, ṣugbọn emi o pa ãyò eso inu wọn.
17
Ọlọrun mi yio sọ wọn nù, nitoriti nwọn kò fetisi tirẹ̀; nwọn o si di alarinkiri lãrin awọn keferi.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14