bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Isaiah 1
Isaiah 1
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 2 →
1
IRAN Isaiah ọmọ Amosi, ti o rí nipa Juda ati Jerusalemu li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda.
2
Gbọ́, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiye: nitori Oluwa ti sọ̀rọ, emi ti bọ́, emi si ti tọ́ awọn ọmọ, nwọn si ti ṣọ̀tẹ si mi.
3
Malũ mọ̀ oluwa rẹ̀, kẹtẹ́kẹtẹ si mọ̀ ibujẹ oluwa rẹ̀: ṣugbọn Israeli kò mọ̀, awọn enia mi kò ronu.
4
A! orilẹ-ède ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, enia ti ẹrù ẹ̀ṣẹ npa, irú awọn oluṣe buburu, awọn ọmọ ti iṣe olubajẹ: nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, nwọn ti mu Ẹni-Mimọ́ Israeli binu, nwọn si ti yipada sẹhìn.
5
Ẽṣe ti a o fi lù nyin si i mọ? ẹnyin o ma ṣọ̀tẹ siwaju ati siwaju: gbogbo ori li o ṣaisàn, gbogbo ọkàn li o si dakú.
6
Lati atẹlẹ̀sẹ titi fi de ori kò si ilera ninu rẹ̀; bikòṣe ọgbẹ́, ipalara, ati õju ti nrà: nwọn kò iti pajumọ, bẹ̃ni a kò iti dì wọn, bẹ̃ni a kò si ti ifi ororo kùn wọn.
7
Ilẹ nyin di ahoro, a fi iná kun ilu nyin: ilẹ nyin, alejo jẹ ẹ run li oju nyin, o si di ahoro, bi eyiti awọn alejo wó palẹ.
8
Ọmọbinrin Sioni li a si fi silẹ bi agọ ninu ọgbà àjara, bi abule ninu ọgbà ẹ̀gúsí, bi ilu ti a dóti.
9
Bikòṣe bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi iyokù diẹ kiun silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, awa iba si ti dabi Gomorra.
10
Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin olori Sodomu; fi eti si ofin Ọlọrun wa, ẹnyin enia Gomorra.
11
Oluwa ni, kini ọ̀pọlọpọ ẹbọ nyin jasi fun mi? emi kún fun ọrẹ sisun agbò, ati fun ọrá ẹran abọ́pa; bẹ̃ni emi kò si ni inu didùn si ẹjẹ akọ malũ, tabi si ti ọdọ-agutan, tabi si ti obúkọ.
12
Nigbati ẹnyin wá lati fi ara hàn niwaju mi, tali o bere eyi lọwọ nyin, lati tẹ̀ agbalá mi?
13
Ẹ má mu ọrẹ asan wá mọ́: turari jasi ohun irira fun mi; oṣù titun ati ọjọ isimi, ìpe ajọ, emi kò le rọju gbà; ẹ̀ṣẹ ni, ani apèjọ ọ̀wọ nì.
14
Oṣù titun nyin ati ajọ ìdasilẹ nyin, ọkàn mi korira; nwọn jasi iyọlẹnu fun mi; o sú mi lati gbà wọn.
15
Nigbati ẹnyin si nà ọwọ́ nyin jade, emi o pa oju mi mọ fun nyin: nitõtọ, nigbati ẹnyin ba gbà adura pupọ, emi kì yio gbọ́: ọwọ́ nyin kún fun ẹ̀jẹ.
16
Ẹ wẹ̀, ki ẹ mọ́; mu buburu iṣe nyin kuro niwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu;
17
Kọ́ lati ṣe rere; wá idajọ, ràn awọn ẹniti a nilara lọwọ, ṣe idajọ alainibaba, gbà ẹjọ opó rò.
18
Oluwa wipe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ̀: bi ẹ̀ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didì; bi nwọn pọ́n bi àlãri, nwọn o dabi irun-agutan.
19
Bi ẹnyin ba fẹ́ ti ẹ si gbọran, ẹnyin o jẹ ire ilẹ na:
20
Ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ̀, ti ẹ si ṣọ̀tẹ, a o fi idà run nyin: nitori ẹnu Oluwa li o ti wi i.
21
Ilu otitọ ha ti ṣe di àgbere! o ti kún fun idajọ ri; ododo ti gbe inu rẹ̀ ri; ṣugbọn nisisiyi, awọn apania.
22
Fadaka rẹ ti di ìdarọ́, ọti-waini rẹ ti dà lu omi:
23
Awọn ọmọ-alade rẹ di ọlọ̀tẹ, ati ẹgbẹ olè: olukuluku nfẹ́ ọrẹ, o si ntọ̀ erè lẹhin: nwọn kò ṣe idajọ alainibaba, bẹ̃ni ọ̀ran opó kò wá sọdọ wọn.
24
Nitorina Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ẹni alagbara Israeli, wipe, A, emi o fi aiya balẹ niti awọn ọtá mi, emi o si gbẹ̀san lara awọn ọtá mi.
25
Emi o yi ọwọ́ mi si ara rẹ, emi o si yọ́ ìdarọ́ rẹ kuro patapata, emi o si mu gbogbo tanganran rẹ kuro:
26
Emi o si mu awọn onidajọ rẹ pada bi igbà iṣãju, ati awọn igbìmọ rẹ bi igbà akọbẹ̀rẹ: lẹhin na, a o pè ọ ni, Ilu ododo, ilu otitọ.
27
Idajọ li a o fi rà Sioni pada, ati awọn ti o pada bọ̀ nipa ododo.
28
Iparun awọn alarekọja pẹlu awọn ẹlẹṣẹ yio wà pọ̀, ati awọn ti o kọ̀ Oluwa silẹ li a o parun.
29
Nitoriti oju yio tì wọn niti igi-nla ti ẹnyin ti fẹ, a o si dãmu nyin niti ọgbà ti ẹnyin ti yàn.
30
Nitori ẹnyin o dabi igi-nla ti ewe rẹ̀ rọ, ati bi ọgbà ti kò ni omi.
31
Alagbara yio si dabi ògùṣọ̀, iṣẹ rẹ̀ yio si dabi ẹta-iná, ati awọn mejeji yio jọ jona pọ̀, ẹnikẹni kì yio si pa wọn.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66