bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Isaiah 41
Isaiah 41
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 40
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 42 →
1
DAKẸ niwaju mi, Ẹnyin erekùṣu; si jẹ ki awọn enia tún agbara wọn ṣe: jẹ ki wọn sunmọ tosí; nigbana ni ki wọn sọ̀rọ: jẹ ki a jumọ sunmọ tosí fun idajọ.
2
Tali o gbe olododo dide lati ìla-õrun wa, ti o pè e si ẹsẹ rẹ̀, ti o fi awọn orilẹ-ède fun u niwaju rẹ̀, ti o si fi ṣe akoso awọn ọba? o fi wọn fun idà rẹ̀ bi ekuru, ati bi akekù iyàngbo fun ọrun rẹ̀.
3
O lepa wọn, o si kọja li alafia; nipa ọ̀na ti kò ti fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ ri.
4
Tali o ti dá a ti o si ti ṣe e, ti o npè awọn iran lati ipilẹṣẹ̀ wá? Emi Oluwa ni; ẹni-ikini, ati pẹlu ẹni-ikẹhìn; Emi na ni.
5
Awọn erekùṣu ri i, nwọn si bẹ̀ru; aiya nfò awọn opin aiye; nwọn sunmọ tosí, nwọn si wá.
6
Olukulùku ràn aladugbo rẹ̀ lọwọ; o si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ mu ara le.
7
Bẹ̃ni gbẹnàgbẹnà ngbà alagbẹdẹ wura niyànju, ati ẹniti nfi ọmọ-owú dán a, ngbà ẹniti nlù ògún niyànju; wipe, o ṣetan fun mimọlù: o si fi iṣo kàn a mọra ki o má le ṣi.
8
Ṣugbọn iwọ, Israeli, ni iranṣẹ mi, Jakobu ẹniti mo ti yàn, iru-ọmọ Abrahamu ọrẹ mi.
9
Ẹniti mo ti mu lati opin aiye wá, ti mo ti pè ọ lati ọdọ awọn olori enia ibẹ, ti mo si wi fun ọ pe, Iwọ ni iranṣẹ mi; mo ti yàn ọ, emi kò si ni ta ọ nù,
10
Iwọ má bẹ̀ru; nitori mo wà pẹlu rẹ; má foyà; nitori emi ni Ọlọrun rẹ: emi o fun ọ ni okun; nitõtọ, emi o ràn ọ lọwọ; nitõtọ, emi o fi ọwọ́ ọ̀tun ododo mi gbe ọ sokè.
11
Kiyesi i, gbogbo awọn ti o binu si ọ ni oju o tì, nwọn o si dãmu: nwọn o dabi asan; awọn ti o si mba ọ jà yio ṣegbe.
12
Iwọ o wá wọn, iwọ kì yio si rí wọn, ani awọn ti o ba ọ jà: awọn ti o mba ọ jagun yio dabi asan, ati bi ohun ti kò si.
13
Nitori emi Oluwa Ọlọrun rẹ yio di ọwọ́ ọ̀tun rẹ mu, emi o wi fun ọ pe, Má bẹ̀ru; emi o ràn ọ lọwọ.
14
Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu kòkoro, ati ẹnyin ọkunrin Israeli; emi o ràn ọ lọwọ, bẹ̃ni Oluwa ati Oluràpada rẹ wi, Ẹni-mimọ́ Israeli.
15
Kiyesi i, emi ti ṣe ọ bi ohun-èlo ipakà mimú titun ti o ni ehín; iwọ o tẹ̀ awọn òke-nla, iwọ o si gún wọn kunná, iwọ o si sọ awọn oke kékèké di iyàngbo.
16
Iwọ o fẹ́ wọn, ẹfũfu yio si fẹ́ wọn lọ, ãjà yio si tú wọn ká: iwọ o si yọ̀ ninu Oluwa, iwọ o si ṣogo ninu Ẹni-Mimọ Israeli.
17
Nigbati talakà ati alaini nwá omi, ti kò si si, ti ahọn wọn si gbẹ fun ongbẹ, emi Oluwa yio gbọ́ ti wọn, emi Ọlọrun Israeli ki yio kọ̀ wọn silẹ.
18
Emi o ṣi odò nibi giga, ati orisún lãrin afonifoji: emi o sọ aginjù di abàta omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi.
19
Emi o fi igi kedari si aginjù, ati igi ṣita, ati mirtili, ati igi oróro; emi o gbìn igi firi ati igi pine ati igi boksi pọ̀ ni aginjù.
20
Ki nwọn ki o le ri, ki nwọn ki o si mọ̀, ki nwọn si gbèro, ki o si le yé won pọ̀, pe, ọwọ́ Oluwa li o ti ṣe eyi, ati pe Ẹni-Mimọ Israeli ni o ti dá a.
21
Mú ẹjọ nyin wá, ni Oluwa wi; mú ọràn dajudaju nyin jade wá, ni ọba Jakobu wi.
22
Jẹ ki wọn mú wọn jade wá, ki wọn si fi ohun ti yio ṣe hàn ni: jẹ ki wọn fi ohun iṣãju hàn, bi nwọn ti jẹ, ki awa ki o lè rò wọn, ki a si mọ̀ igbẹ̀hin wọn; tabi ki nwọn sọ ohun wọnni ti mbọ̀ fun wa.
23
Fi ohun ti mbọ̀ lẹhìn eyi hàn, ki awa ki o le mọ̀ pe ọlọrun ni nyin: nitõtọ, ẹ ṣe rere, tabi ẹ ṣe buburu, ki ẹ̀ru le bà wa, ki a le jumọ ri i.
24
Kiyesi i, lati nkan asan ni nyin, iṣẹ nyin si jẹ asan: irira ni ẹniti o yàn nyin.
25
Emi ti gbé ẹnikan dide lati ariwa, on o si wá: lati ilà-õrun ni yio ti ké pe orukọ mi: yio si wá sori awọn ọmọ-alade bi sori àmọ, ati bi alamọ̀ ti itẹ̀ erupẹ.
26
Tani o ti fi hàn lati ipilẹ̀ṣẹ, ki awa ki o le mọ̀? ati nigba iṣãju, ki a le wi pe, Olododo ni on? nitõtọ, kò si ẹnikan ti o fi hàn, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o sọ ọ, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o gbọ́ ọ̀rọ nyin.
27
Ẹni-ikini o wi fun Sioni pe, Wò o, on na nĩ: emi o fi ẹnikan ti o mú ihinrere wá fun Jerusalemu.
28
Nitori mo wò, kò si si ẹnikan; ani ninu wọn, kò si si olugbimọ̀ kan, nigbati mo bere lọwọ wọn, kò si ẹniti o le dahùn ọ̀rọ kan.
29
Kiyesi i, asan ni gbogbo wọn; asan ni iṣẹ wọn; ẹfũfu ati rudurudu ni ere didà wọn.
← Chapter 40
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 42 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66