bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Isaiah 7
Isaiah 7
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 8 →
1
O si ṣe li ọjọ Ahasi ọmọ Jotamu ọmọ Ussiah, ọba Juda, ti Resini, ọba Siria, ati Peka ọmọ Remaliah, ọba Israeli, gokè lọ si Jerusalemu lati jà a li ogun, ṣugbọn nwọn kò le bori rẹ̀.
2
A si sọ fun ile Dafidi pe, Siria ba Efraimu dìmọlú. Ọkàn rẹ̀ si mì, ati ọkàn awọn enia rẹ̀ bi igi igbo ti imì nipa ẹfũfu.
3
Oluwa si sọ fun Isaiah pe, Jade nisisiyi, lọ ipade Ahasi, iwọ, ati Ṣeaja-ṣubu ọmọ rẹ, ni ipẹkun oju iṣàn ikũdu ti apa oke, li opopo pápa afọṣọ;
4
Si sọ fun u pe, Kiyesara, ki o si gbe jẹ, má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe jaiya nitori ìru meji igi iná ti nrú ẹ̃fin wọnyi nitori ibinu mimuna Resini pẹlu Siria, ati ti ọmọ Remaliah.
5
Nitori Siria, Efraimu, ati ọmọ Remaliah ti gbìmọ ibi si ọ wipe.
6
Ẹ jẹ ki a gòke lọ si Juda, ki a si bà a ninu jẹ, ẹ si jẹ ki a ṣe ihò ninu rẹ̀ fun ara wa, ki a si gbe ọba kan kalẹ lãrin rẹ̀, ani ọmọ Tabeali:
7
Bayi ni Oluwa Jehofah wi, Ìmọ na kì yio duro, bẹ̃ni ki yio ṣẹ.
8
Nitori ori Siria ni Damasku, ori Damasku si ni Resini; ninu ọdun marunlelọgọta li a o fọ Efraimu ti ki yio si jẹ́ enia mọ.
9
Ori Efraimu si ni Samaria, ori Samaria si ni ọmọ Remaliah. Bi ẹnyin ki yio ba gbagbọ́, lotitọ, a ki yio fi idi nyin mulẹ.
10
Oluwa si tun sọ fun Ahasi pe,
11
Bere àmi kan lọwọ Oluwa Ọlọrun rẹ; bere rẹ̀, ibã jẹ ni ọgbun tabi li okè.
12
Ṣugbọn Ahasi wipe, Emi ki yio bere, bẹ̃ni emi ki yio dán Oluwa wò.
13
On si wipe, Ẹ gbọ́ nisisiyi ẹnyin ara ile Dafidi, iṣe ohun kekere fun nyin lati dá enia lagara, ṣugbọn ẹnyin o ha si dá Ọlọrun mi lagara pẹlu bi?
14
Nitorina, Oluwa tikalarẹ̀ yio fun nyin li àmi kan, kiyesi i, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rẹ̀ ni Immanueli.
15
Ori-amọ ati oyin ni yio ma jẹ, ki o le ba mọ̀ bi ati kọ̀ ibi, ati bi ati yàn ire.
16
Nitoripe, ki ọmọ na ki o to mọ̀ bi ati kọ̀ ibi, ati bi ati yàn ire, ilẹ ti iwọ korira yio di ikọ̀silẹ lọdọ ọba rẹ̀ mejeji.
17
Oluwa yio si mu ọjọ ti kò si bẹ̃ ri wá sori rẹ ati sori awọn enia rẹ, ati sori ile baba rẹ, lati ọjọ ti Efraimu ti lọ kuro lọdọ Juda, ani ọba Assiria.
18
Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio kọ si eṣinṣin ti o wà li apa ipẹkun odo ṣiṣàn nlanla Egipti, ati si oyin ti o wà ni ilẹ Assiria.
19
Nwọn o si wá, gbogbo wọn o si bà sinu afonifojì ijù, ati sinu pàlapala okuta, ati lori gbogbo ẹgun, ati lori eweko gbogbo.
20
Li ọjọ kanna ni Oluwa yio fi abẹ ti a yá, eyini ni, awọn ti ihà keji odo nì, ọba Assiria, fá ori ati irun ẹsẹ, yio si run irungbọn pẹlu.
21
Yio si ṣe li ọjọ na, enia kan yio si tọ́ ọmọ malu kan ati agutan meji;
22
Yio si ṣe, nitori ọ̀pọlọpọ wàra ti nwọn o mu wá, yio ma jẹ ori-amọ; nitori ori-amọ ati oyin ni olukulùku ti o ba kù ni ãrin ilẹ na yio ma jẹ.
23
Yio si ṣe li ọjọ na, ibi gbogbo yio ri bayi pe, ibi ti ẹgbẹrun àjara ti wà fun ẹgbẹrun owo fadakà yio di ti ẹwọn ati ẹgun.
24
Pẹlu ọfà ati ọrun ni enia yio wá ibẹ, nitoripe gbogbo ilẹ na yio di ẹwọn ati ẹgun.
25
Ati lori gbogbo okè kékèké ti a o fi ọkọ́ tu, ẹ̀ru ẹ̀wọn ati ẹ̀gun ki yio de ibẹ̀: ṣugbọn yio jẹ ilu ti a ndà malũ lọ, ati ibi itẹ̀mọlẹ fun awọn ẹran kékèké.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66