bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Isaiah 9
Isaiah 9
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 10 →
1
ṢUGBỌN iṣuju na kì yio wà nibiti wahalà mbẹ nisisiyi, gẹgẹ bi ìgba iṣãju ti mu itìju wá si ilẹ Sebuloni ati ilẹ Naftali, bẹ̃ni ìgba ikẹhin yio mu ọla wá si ọ̀na okun, niha ẹkùn Jordani, Galili awọn orilẹ-ède.
2
Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ́ si.
3
Iwọ ti mu orilẹ-ède nì bi si i pupọ̀pupọ̀, iwọ si sọ ayọ̀ di pupọ̀ fun u: nwọn nyọ̀ niwaju rẹ gẹgẹ bi ayọ̀ ikore, ati gẹgẹ bi enia iti yọ̀ nigbati nwọn npin ikogun.
4
Nitori iwọ ṣẹ́ ajàga-irú rẹ̀, ati ọpá ejika rẹ̀, ọgọ aninilara rẹ̀, gẹgẹ bi li ọjọ Midiani.
5
Nitori gbogbo ihamọra awọn ologun ninu irọkẹ̀kẹ, ati aṣọ ti a yi ninu ẹ̀jẹ, yio jẹ fun ijoná ati igi iná.
6
Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọ̀ran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia.
7
Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.
8
Oluwa rán ọ̀rọ si Jakobu, o si ti bà lé Israeli.
9
Gbogbo enia yio si mọ̀ ọ, Efraimu ati awọn ti ngbe Samaria, ti nwi ninu igberaga, ati lile aiya pe,
10
Briki wọnni ṣubu lu ilẹ, ṣugbọn awa o fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: a ke igi sikamore lu ilẹ, ṣugbọn a o fi igi kedari pãrọ wọn.
11
Nitorina li Oluwa yio gbe awọn aninilara Resini dide si i, yio si dá awọn ọtá rẹ̀ pọ̀.
12
Awọn ara Siria niwaju, ati awọn Filistini lẹhin: nwọn o si fi gbogbo ẹnu jẹ Israeli run. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
13
Awọn enia na kọ yipada si ẹniti o lù wọn, bẹ̃ni nwọn kò wá Oluwa awọn ọmọ-ogun.
14
Nitorina ni Oluwa yio ke ori ati irù, imọ̀-ọpẹ ati koriko-odo kuro ni Israeli, li ọjọ kan.
15
Agbà ati ọlọla, on li ori, ati wolĩ ti nkọni li eké, on ni irù.
16
Nitori awọn olori enia yi mu wọn ṣìna: awọn ti a si tọ́ li ọ̀na ninu wọn li a parun.
17
Nitorina ni Oluwa kì yio ṣe ni ayọ̀ ninu ọdọ-ọmọkunrin wọn, bẹ̃ni ki yio ṣãnu fun awọn alainibaba ati opo wọn: nitori olukuluku wọn jẹ agabagebe ati oluṣe-buburu, olukuluku ẹnu nsọ wère. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
18
Nitori ìwa-buburu njo bi iná: yio jo ẹwọn ati ẹgún run, yio si ràn ninu pàntiri igbó, nwọn o si goke lọ bi ẹ̃fin iti goke.
19
Nipa ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ilẹ fi ṣõkùn, awọn enia yio dabi igi iná, ẹnikan kì yio dá arakunrin rẹ̀ si.
20
On o si jajẹ li ọwọ́ ọ̀tun, ebi o si pa a; on o si jẹ li ọwọ́ osì; nwọn kì yio si yo: olukuluku enia yio si jẹ ẹran-ara apa rẹ̀.
21
Manasse o jẹ Efraimu; Efraimu o si jẹ Manasse: awọn mejeji o dojukọ Juda. Ni gbogbo eyi, ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 53
Chapter 54
Chapter 55
Chapter 56
Chapter 57
Chapter 58
Chapter 59
Chapter 60
Chapter 61
Chapter 62
Chapter 63
Chapter 64
Chapter 65
Chapter 66
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66