bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Deuteronomy 13
Deuteronomy 13
Yoruba 2010
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 14 →
1
“Bí ẹnìkan bá di wolii láàrin yín, tabi tí ó ń lá àlá, tí ń sọ nípa àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí yóo ṣẹlẹ̀,
2
tí gbogbo nǹkan tí ó ń sọ sì ń rí bẹ́ẹ̀; bí ó bá wí pé kí ẹ wá lọ bọ oriṣa mìíràn tí ẹ kò mọ̀ rí,
3
ẹ kò gbọdọ̀ dá wolii tabi alálàá náà lóhùn, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ń dán yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn òun tọkàntọkàn.
4
OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa tẹ̀lé, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù. Ẹ máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì máa gbọ́ tirẹ̀; ẹ máa sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.
5
Ṣugbọn pípa ni kí ẹ pa wolii tabi alálàá náà, nítorí pé ó ń kọ yín láti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú. Ẹ níláti pa olúwarẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ mú kí ẹ kọ ẹ̀yìn sí ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti là sílẹ̀ fun yín láti máa rìn, nítorí náà ẹ gbọdọ̀ yọ nǹkan burúkú náà kúrò láàrin yín.
6
“Bí ẹnikẹ́ni bá ń tàn ọ́ níkọ̀kọ̀ pé kí o lọ bọ oriṣa-koriṣa kan, tí ìwọ tabi àwọn baba rẹ kò bọ rí, olúwarẹ̀ kì báà jẹ́ arakunrin rẹ, tíí ṣe ọmọ ìyá rẹ, tabi ọmọ rẹ, lọkunrin tabi lobinrin, tabi aya rẹ, tí ó dàbí ẹyin ojú rẹ, tabi ọ̀rẹ́ rẹ tí o fẹ́ràn ju ẹ̀mí ara rẹ lọ;
7
oriṣa yìí kì báà jẹ́ èyí tí ó wà nítòsí, tí àwọn ará agbègbè yín ń bọ, tabi èyí tí ó jìnnà réré, tí àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ òkèèrè ń bọ.
8
O kò gbọdọ̀ gbọ́ tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ dá a lóhùn. O kò gbọdọ̀ ṣàánú fún un, o kò sì gbọdọ̀ bò ó.
9
Pípa ni kí o pa á, ìwọ gan-an ni kí o kọ́ sọ òkúta lù ú, kí àwọn eniyan yòókù tó kó òkúta bò ó.
10
Ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí tí ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde kúrò ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti.
11
Gbogbo ọmọ Israẹli yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo sì bà wọ́n, ẹnikẹ́ni kò sì ní hu irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láàrin yín.
12
“Bí ẹ bá gbọ́, ní ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti máa gbé, pé,
13
àwọn eniyan lásán kan láàrin yín ń tan àwọn ará ìlú náà jẹ, wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ bọ oriṣa.’
14
Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ náà. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ó sì dáa yín lójú pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín,
15
idà ni kí ẹ fi pa àwọn tí wọn ń gbé ìlú náà. Ẹ pa wọ́n run patapata, ati gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀; ẹ fi idà pa gbogbo wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.
16
Ẹ kó gbogbo ìkógun tí ẹ bá rí ninu ìlú náà jọ sí ààrin ìgboro rẹ̀, kí ẹ sì dáná sun gbogbo rẹ̀ bí ẹbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun yín. Ìlú náà yóo di àlàpà títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ tún un kọ́ mọ́.
17
Àwọn ìkógun yìí jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan èyíkéyìí ninu wọn kí OLUWA lè yí ibinu gbígbóná rẹ̀ pada, kí ó ṣàánú fun yín, kí ó sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín.
18
Ẹ máa gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34