bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Deuteronomy 21
Deuteronomy 21
Yoruba 2010
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 22 →
1
“Bí ẹ bá rí òkú eniyan tí wọ́n pa sinu igbó, lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ kò sì mọ ẹni tí ó pa á,
2
kí àwọn àgbààgbà ati àwọn adájọ́ yín jáde wá, kí wọ́n wọn ilẹ̀ láti ibi tí wọ́n pa ẹni náà sí títí dé gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká ibẹ̀.
3
Kí àwọn àgbààgbà ìlú tí ó bá súnmọ́ ibẹ̀ jùlọ wá ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí ẹnikẹ́ni kò tíì so àjàgà mọ́ lọ́rùn láti fi ṣiṣẹ́ rí,
4
kí wọ́n mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù náà lọ sí àfonífojì tí ó ní odò tí ń ṣàn, tí ẹnikẹ́ni kò gbin ohunkohun sí rí, kí wọ́n sì lọ́ ọ̀dọ́ mààlúù náà lọ́rùn pa níbẹ̀.
5
Kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, bá wọn lọ pẹlu; nítorí àwọn ni OLUWA Ọlọrun yín yàn láti máa ṣe alufaa ati láti máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA; ati pé àwọn ni OLUWA Ọlọrun yàn láti parí àríyànjiyàn ati ẹjọ́.
6
Kí gbogbo àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà ní ìlú náà wẹ ọwọ́ wọn sórí mààlúù tí wọ́n ti lọ́ lọ́rùn pa yìí.
7
Kí wọ́n wí pé, ‘A kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ẹni tí ó pa á.
8
OLUWA, dáríjì Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí o ti rà pada, má sì ṣe jẹ àwọn eniyan Israẹli níyà nítorí ikú aláìṣẹ̀ yìí. Ṣugbọn dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà jì wọ́n.’
9
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ ara yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀, bí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA.
10
“Nígbà tí ẹ bá lọ bá àwọn ọ̀tá yín jagun, tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi wọ́n le yín lọ́wọ́, tí ẹ bá sì kó wọn lẹ́rú;
11
tí ẹ bá rí arẹwà obinrin kan láàrin àwọn ẹrú náà tí ó wù yín láti fi ṣe aya fún ara yín.
12
Ẹ mú un wá sí ilẹ̀ yín ẹ fá irun orí rẹ̀, kí ẹ sì gé èékánná ọwọ́ rẹ̀.
13
Ẹ bọ́ aṣọ ẹrú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó wà ní ilẹ̀ yín, kí ó sì máa ṣọ̀fọ̀ baba ati ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan. Lẹ́yìn náà ẹ lè wọlé tọ̀ ọ́, kí ẹ sì di tọkọtaya.
14
Lẹ́yìn náà, tí kò bá wù yín mọ́ ẹ níláti fún un láyè kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá wù ú, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ tà á bí ẹrú, ẹ kò sì gbọdọ̀ lò ó ní ìlò ẹrú, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bá a lòpọ̀ rí.
15
“Bí ẹnìkan bá ní iyawo meji, tí ó fẹ́ràn ọ̀kan, tí kò sì fẹ́ràn ekeji, tí àwọn mejeeji bímọ fún un, tí ó bá jẹ́ pé iyawo tí kò fẹ́ràn ni ó bí àkọ́bí ọmọkunrin rẹ̀ fún un,
16
ní ọjọ́ tí yóo bá ṣe ètò bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóo ṣe pín ogún rẹ̀, kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, kí ó pín ogún fún ọmọ ẹni tí ó fẹ́ràn gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí, kí ó sì ṣe ọmọ ẹni tí kò fẹ́ràn bí ẹni pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí rẹ̀.
17
Ṣugbọn kí ó fihàn pé ọmọ obinrin tí òun kò fẹ́ràn yìí ni àkọ́bí òun, kí ó sì fún un ní ogún tí ó tọ́ sí i ninu ohun ìní rẹ̀. Òun ṣá ni àkọ́bí rẹ̀, òun sì ni ẹ̀tọ́ àkọ́bí tọ́ sí.
18
“Bí ẹnìkan bá bí ọmọkunrin kan, tí ó jẹ́ aláìgbọràn ati olórí kunkun ọmọ, tí kì í gbọ́, tí kì í sì í gba ti àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n bá a wí títí, ṣugbọn tí kò gbọ́,
19
kí baba ati ìyá rẹ̀ mú un wá siwaju àwọn àgbààgbà ìlú náà, ní ẹnu bodè ìlú tí ó ń gbé,
20
kí wọ́n wí fún àwọn àgbààgbà ìlú náà pé, ‘Ọmọ wa yìí ya olóríkunkun ati aláìgbọràn, kì í gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Oníjẹkújẹ ati onímukúmu sì ni.’
21
Lẹ́yìn náà kí àwọn ọkunrin ìlú sọ ọ́ ní òkúta pa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó ṣe yọ ibi kúrò láàrin yín; gbogbo Israẹli yóo gbọ́, wọn yóo sì bẹ̀rù.
22
“Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ kan, tí ó jẹ́ pé ikú ni ìjìyà irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ẹ bá so ó kọ́ sórí igi,
23
òkú rẹ̀ kò gbọdọ̀ sun orí igi náà. Ẹ níláti sin ín ní ọjọ́ náà, nítorí ẹni ìfibú Ọlọrun ni ẹni tí a bá so kọ́ orí igi, ẹ kò gbọdọ̀ sọ ilẹ̀ yín tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín di aláìmọ́.
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 22 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34