bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Deuteronomy 26
Deuteronomy 26
Yoruba 2010
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 27 →
1
“Nígbà tí o bá dé orí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ, tí o gbà á, tí o sì ń gbé inú rẹ̀,
2
mú ninu àkọ́so èso ilẹ̀ náà sinu agbọ̀n kan, kí o sì gbé e lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun rẹ yóo yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.
3
Tọ alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Mò ń wí fún OLUWA Ọlọrun mi lónìí pé, mo ti dé ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wa láti fún wa.’
4
“Alufaa yóo gba agbọ̀n èso náà ní ọwọ́ rẹ, yóo sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ.
5
Lẹ́yìn náà, o óo wí báyìí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Ará Aramea, alárìnká, ni baba ńlá mi, ó lọ sí ilẹ̀ Ijipti, ó sì jẹ́ àlejò níbẹ̀. Wọn kò pọ̀ rárá tẹ́lẹ̀, ṣugbọn níbẹ̀ ni wọ́n ti di pupọ, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè ńlá, tí ó lágbára, tí ó sì lókìkí.
6
Àwọn ará Ijipti lò wá ní ìlò ìkà, wọ́n pọ́n wa lójú, wọ́n sì mú wa sìn bí ẹrú.
7
A bá kígbe pe OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa; ó gbọ́ ohùn wa, ó rí ìpọ́njú, ati ìṣẹ́, ati ìjìyà wa.
8
OLUWA fi agbára rẹ̀ kó wa jáde láti Ijipti, pẹlu àwọn iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu.
9
Ó kó wa wá sí ìhín, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí; ilẹ̀ tí ó ní ọ̀rá tí ó kún fún wàrà ati oyin.
10
Nítorí náà, nisinsinyii, mo mú àkọ́so èso ilẹ̀ tí ìwọ OLUWA ti fi fún mi wá.’ “Lẹ́yìn náà, gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì sìn ín;
11
kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ fún ohun tí OLUWA fún ìwọ ati ìdílé rẹ, kí àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò tí ń gbé ààrin yín náà sì máa bá ọ ṣe àjọyọ̀.
12
“Ní ọdún kẹtakẹta, tíí ṣe ọdún ìdámẹ́wàá, tí o bá ti dá ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko rẹ, kí o kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, kí wọ́n lè máa jẹ àjẹyó ninu ìlú yín.
13
Lẹ́yìn náà, kí o wí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá tíí ṣe ohun ìyàsímímọ́ ni mo ti mú kúrò ninu ilé mi, mo sì ti fi fún àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo àṣẹ tí o pa fún mi. N kò rú èyíkéyìí ninu àwọn òfin rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì gbàgbé wọn.
14
N kò jẹ ninu ìdámẹ́wàá mi nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò kó èyíkéyìí jáde kúrò ninu ilé mi nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, tabi kí n fi èyíkéyìí ninu wọn bọ òkú ọ̀run. Gbogbo ohun tí o wí ni mo ti ṣe, OLUWA Ọlọrun mi, mo sì ti pa gbogbo àṣẹ rẹ mọ́.
15
Bojúwo ilẹ̀ láti ibùgbé mímọ́ rẹ lọ́run, kí o sì bukun Israẹli, àwọn eniyan rẹ, ati ilẹ̀ tí o ti fi fún wa gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wa, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.’
16
“OLUWA Ọlọrun rẹ pàṣẹ fún ọ lónìí, pé kí o máa pa gbogbo ìlànà ati òfin wọnyi mọ́. Nítorí náà, máa pa gbogbo wọn mọ́ tọkàntọkàn.
17
O ti fi ẹnu ara rẹ sọ lónìí pé, OLUWA ni Ọlọrun rẹ, ati pé o óo máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, o óo máa pa gbogbo ìlànà ati òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, o óo sì máa gbọ́ tirẹ̀.
18
OLUWA pàápàá sì ti sọ lónìí pé, eniyan òun ni ọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ, ati pé kí o pa gbogbo òfin òun mọ́.
19
Ó ní òun óo gbé ọ ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó dá lọ. O óo níyì jù wọ́n lọ; o óo ní òkìkí jù wọ́n lọ, o óo sì lọ́lá jù wọ́n lọ. O óo jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.”
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 27 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34