bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Deuteronomy 25
Deuteronomy 25
Yoruba 2010
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 26 →
1
“Bí èdè-àìyedè kan bá bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ meji, tí wọ́n bá lọ sí ilé ẹjọ́, tí àwọn adájọ́ sì dá ẹjọ́ náà fún wọn, tí wọ́n dá ẹni tí ó jàre láre, tí wọ́n sì dá ẹni tí ó jẹ̀bi lẹ́bi,
2
bí ó bá jẹ́ pé nínà ni ó yẹ kí wọ́n na ẹni tí ó jẹ̀bi, ẹni náà yóo dọ̀bálẹ̀ níwájú adájọ́, wọn yóo sì nà án ní iye ẹgba tí ó bá tọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
3
Ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ nà án ju ogoji ẹgba lọ, ohun ìtìjú ni yóo jẹ́ fún un ní gbangba, bí wọ́n bá nà án jù bẹ́ẹ̀ lọ.
4
“Ẹ kò gbọdọ̀ dí mààlúù lẹ́nu nígbà tí ẹ bá ń lò ó láti fi pa ọkà.
5
“Bí àwọn arakunrin meji bá jùmọ̀ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan ninu wọn sì kú láìní ọmọkunrin, aya ẹni tí ó kú kò gbọdọ̀ lọ fẹ́ ará ìta tabi àlejò. Arakunrin ọkọ rẹ̀ ni ó gbọdọ̀ ṣú u lópó, kí ó sì máa ṣe gbogbo ẹ̀tọ́ tí ó bá yẹ fún obinrin náà.
6
Wọn yóo ka ọmọkunrin kinni tí opó yìí bá bí sí ọmọ ọkọ rẹ̀ tí ó kú, kí orúkọ ọkọ rẹ̀ náà má baà parẹ́ ní Israẹli.
7
Bí ọkunrin yìí kò bá wá fẹ́ ṣú aya arakunrin rẹ̀ tí ó kú lópó, obinrin náà yóo tọ àwọn àgbààgbà lọ ní ẹnubodè, yóo sì wí pé, ‘Arakunrin ọkọ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arakunrin rẹ̀ ró ní Israẹli, ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arakunrin ọkọ mi.’
8
Àwọn àgbààgbà ìlú yóo pe ọkunrin náà, wọn óo bá a sọ̀rọ̀, bí ó bá kọ̀ jálẹ̀, tí ó wí pé, ‘Èmi kò fẹ́ fẹ́ ẹ,’
9
Lẹ́yìn náà, obinrin náà yóo tọ̀ ọ́ lọ lójú gbogbo àwọn àgbààgbà, yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo tutọ́ sí i lójú, yóo sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ẹni tí ó bá kọ̀ láti kọ́ ilé arakunrin rẹ̀.’
10
Wọn yóo sì máa pe ìdílé rẹ̀ ní ìdílé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀.
11
“Bí ọkunrin meji bá ń jà, tí iyawo ọ̀kan ninu wọn bá sáré wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ tí wọn ń lù, tí ó bá fa nǹkan ọkunrin ẹni tí ń lu ọkọ rẹ̀ yìí,
12
gígé ni kí ẹ gé ọwọ́ rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá.
13
“O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí ìwọ̀n meji ninu àpò rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi.
14
O kò gbọdọ̀ ní oríṣìí òṣùnwọ̀n meji ninu ilé rẹ, kí ọ̀kan kéré, kí ekeji sì tóbi.
15
Ṣugbọn ìwọ̀n ati òṣùnwọ̀n rẹ gbọdọ̀ péye, kí ọjọ́ rẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ.
16
Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe aiṣootọ, ìríra ni lójú OLUWA Ọlọrun yín.
17
“Ẹ ranti ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí yín nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti Ijipti.
18
Wọn kò bẹ̀rù Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n gbógun tì yín lójú ọ̀nà nígbà tí ó ti rẹ̀ yín, wọ́n sì pa gbogbo àwọn tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn.
19
Nítorí náà nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fun yín ní ìṣẹ́gun lórí gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n wà ní àyíká yín, ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, pípa ni kí ẹ pa àwọn ará Amaleki run lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé.
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 26 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34