bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Deuteronomy 20
Deuteronomy 20
Yoruba 2010
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 21 →
1
“Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, tí ẹ bá rí ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wà pẹlu yín.
2
Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ojú ogun, kí alufaa jáde kí ó sì bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, kí ó wí fún wọn pé,
3
‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, tí ẹ̀ ń lọ sí ojú ogun lónìí láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àyà yín já, ẹ̀rù kò sì gbọdọ̀ bà yín, ẹ kò gbọdọ̀ wárìrì tabi kí ẹ jẹ́ kí jìnnìjìnnì dà bò yín.
4
Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ati láti fun yín ní ìṣẹ́gun.’
5
“Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun yóo wí fún àwọn eniyan náà pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ilé titun, tí kò tíì yà á sí mímọ́? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo ya ilé rẹ̀ sí mímọ́.
6
Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbin ọgbà àjàrà, tí kò sì tíì jẹ ninu èso rẹ̀? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo jẹ èso ọgbà àjàrà rẹ̀.
7
Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ iyawo sọ́nà tí kò tíì gbé e wọlé? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo fẹ́ iyawo rẹ̀.’
8
“Àwọn ọ̀gágun yóo tún bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ẹ̀rù ń bà, tabi tí àyà rẹ̀ ń já? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé, kí ó má baà kó ojora bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.’
9
Nígbà tí àwọn ọ̀gágun bá parí ọ̀rọ̀ tí wọn ń bá àwọn eniyan náà sọ, wọn óo yan àwọn kan tí wọn óo máa ṣe aṣaaju ìsọ̀rí-ìsọ̀rí àwọn jagunjagun.
10
“Bí ẹ bá ti súnmọ́ ìlú tí ẹ fẹ́ bá jagun, ẹ kọ́ rán iṣẹ́ alaafia sí wọn.
11
Bí wọ́n bá rán iṣẹ́ alaafia pada, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn wọn fun yín, kí ẹ kó gbogbo àwọn ará ìlú náà lẹ́rú kí wọ́n sì máa sìn yín.
12
Ṣugbọn bí wọ́n bá kọ̀, tí àwọn náà dìde ogun si yín, ẹ dó ti ìlú náà.
13
Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fi ìlú náà le yín lọ́wọ́, kí ẹ fi idà pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà níbẹ̀.
14
Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn obinrin ati àwọn ọmọ wọn sí, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo dúkìá yòókù tí ó wà ninu ìlú náà, kí ẹ kó gbogbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín, kí ẹ máa lo gbogbo dúkìá àwọn ọ̀tá yín tí OLUWA Ọlọrun yín ti fun yín.
15
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sí àwọn ìlú tí ó jìnnà sí yín, tí kì í ṣe àwọn ìlú orílẹ̀-èdè tí ó wà níhìn-ín.
16
“Ṣugbọn gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín, gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ kò gbọdọ̀ dá ohun alààyè kan sí ninu wọn.
17
Rírun ni kí ẹ run gbogbo wọn patapata, gbogbo àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Kenaani, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi; gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti pa á láṣẹ.
18
Kí wọ́n má baà kọ yín ní ìkọ́kúkọ̀ọ́, kí ẹ má baà máa ṣe oríṣìíríṣìí àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń bọ àwọn oriṣa wọn, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín.
19
“Nígbà tí ẹ bá dó ti ìlú kan fún ìgbà pípẹ́, tí ẹ bá ń bá ìlú náà jagun tí ẹ fẹ́ gbà á, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ́ àwọn igi eléso wọn lulẹ̀ ní ìbẹ́kúbẹ̀ẹ́. Jíjẹ ni kí ẹ máa jẹ èso igi wọn, ẹ kò gbọdọ̀ gé wọn lulẹ̀. Àbí eniyan ni igi inú igbó, tí ẹ óo fi máa gbé ogun tì í?
20
Àwọn igi tí ẹ bá mọ̀ pé èso wọn kìí ṣe jíjẹ nìkan ni kí ẹ máa gé, kí ẹ máa fi ṣe àtẹ̀gùn, tí ẹ fi lè wọ ìlú náà, títí tí ọwọ́ yín yóo fi tẹ̀ ẹ́.
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 21 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34