bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Jeremiah 12
Jeremiah 12
Yoruba 2010
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 13 →
1
Olódodo ni ọ́, OLUWA, nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́; sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ. Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú?
2
O gbìn wọ́n, wọ́n ta gbòǹgbò; wọ́n dàgbà, wọ́n so èso; orúkọ rẹ kò jìnnà sẹ́nu wọn, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí ọ.
3
Ṣugbọn ìwọ OLUWA mọ̀ mí, O rí mi, o sì ti yẹ ọkàn mi wò o mọ èrò mi sí ọ. Fà wọ́n jáde bí aguntan tí wọn ń mú lọ pa, yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìparun.
4
Yóo ti pẹ́ tó, tí ilẹ̀ náà yóo máa ṣọ̀fọ̀, tí koríko oko yóo rọ? Nítorí iṣẹ́ burúkú àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ ṣègbé, nítorí àwọn eniyan ń wí pé, “Kò ní rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wa.”
5
OLUWA ní, “Bí o bá àwọn tí ń fi ẹsẹ̀ sáré sáré, tí ó bá rẹ̀ ọ́, báwo ni o ṣe lè bá ẹṣin sáré? Bí o bá sì ń ṣubú ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, báwo ni o óo ti ṣe nígbà tí o bá dé aṣálẹ̀ Jọdani?
6
Nítorí pé àwọn arakunrin rẹ pàápàá ati àwọn ará ilé baba rẹ ti hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọ; àwọn gan-an ni wọ́n ń ṣe èké rẹ: Má gbẹ́kẹ̀lé wọn, bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rere sí ọ.”
7
OLUWA wí pé, “Mo ti kọ ilé mi sílẹ̀; mo ti kọ ogún tí a pín fún mi sílẹ̀. Mo ti fa ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
8
Ogún mi ti dàbí kinniun inú igbó sí mi, ó ti sọ̀rọ̀ burúkú sí mi; nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.
9
Ṣé ogún mi ti dàbí ẹyẹ igún aláwọ̀ adíkálà ni? Ṣé àwọn ẹyẹ igún ṣùrù bò ó ni? Ẹ lọ pe gbogbo àwọn ẹranko igbó jọ, ẹ kó wọn wá jẹun.
10
Ọpọlọpọ àwọn darandaran ni wọ́n ti ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, wọ́n ti tẹ oko mi mọ́lẹ̀, wọ́n sọ oko mi dáradára di aṣálẹ̀.
11
Wọ́n sọ ọ́ di ahoro, ilẹ̀ pàápàá ń ráhùn sí mi. Wọ́n ti sọ gbogbo ilẹ̀ náà di ahoro, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún un.
12
Àwọn apanirun ti dé sí gbogbo àwọn òkè inú pápá, nítorí pé idà Ọlọrun ni ó ń run eniyan, jákèjádò ilẹ̀ náà; ẹnikẹ́ni kò ní alaafia,
13
Ọkà baali ni wọ́n gbìn, ṣugbọn ẹ̀gún ni wọ́n kórè. Wọ́n ṣe làálàá, ṣugbọn wọn kò jèrè kankan. Ojú yóo tì wọ́n nígbà ìkórè, nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.”
14
Ohun tí OLUWA sọ nípa gbogbo àwọn aládùúgbò burúkú mi nìyí, àwọn tí wọn ń jí bù lára ilẹ̀ tí mo fún Israẹli, àwọn eniyan mi. Ó ní, “N óo kó wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn; n óo sì kó àwọn ọmọ Juda kúrò láàrin wọn.
15
Lẹ́yìn tí mo bá kó wọn kúrò tán, n óo pada ṣàánú wọn, n óo dá olukuluku pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.
16
Nígbà tí ó bá yá, bí wọ́n bá fi tọkàntọkàn kọ́ àṣà àwọn eniyan mi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ mi búra, tí wọn ń wí pé, ‘Bí OLUWA Ọlọrun ti wà láàyè’, bí àwọn náà ṣe kọ́ àwọn eniyan mi láti máa fi orúkọ Baali búra, n óo fi ìdí wọn múlẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi.
17
Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣe àìgbọràn, n óo yọ ọ́ kúrò patapata, n óo sì pa á run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52