bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Jeremiah 27
Jeremiah 27
Yoruba 2010
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 28 →
1
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ọmọ Josaya, OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀; ó ní:
2
“Ṣe àjàgà kan pẹlu okùn rẹ̀ kí o sì fi bọ ara rẹ lọ́rùn.
3
Àwọn ikọ̀ kan wá sí ọ̀dọ̀ Sedekaya, ọba Juda, ní Jerusalẹmu, láti ọ̀dọ̀ ọba Edomu ati ọba Moabu, ọba àwọn ọmọ Amoni, ọba Tire, ati ọba Sidoni wá, rán wọn pada sí àwọn oluwa wọn,
4
sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n sọ fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní
5
òun ni òun fi agbára ńlá òun dá ayé: ati eniyan ati ẹranko tí wọ́n wà lórí ilẹ̀; ẹni tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun óo sì fi wọ́n fún.
6
Ó ní òun ti fún Nebukadinesari, ọba Babiloni iranṣẹ òun, ní gbogbo àwọn ilẹ̀ wọnyi, òun sì ti fún un ni àwọn ẹranko inú igbó kí wọn máa ṣe iranṣẹ rẹ̀.
7
Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóo máa ṣe ẹrú òun ati ọmọ rẹ̀, ati ọmọ ọmọ rẹ̀, títí àkókò tí ilẹ̀ òun pàápàá yóo fi tó, tí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba ńláńlá yóo sì kó o lẹ́rú.”
8
OLUWA ní, “Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè tabi ìjọba kan bá kọ̀, tí wọn kò sin Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí wọn kò sì ti ọrùn wọn bọ àjàgà rẹ̀, ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ni n óo fi jẹ orílẹ̀-èdè náà níyà títí n óo fi fà á lé ọba Babiloni lọ́wọ́.
9
Nítorí náà, ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín, ati àwọn awoṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín ati àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, ati àwọn oṣó yín, tí wọn ń sọ fun yín pé ẹ kò ní di ẹrú ọba Babiloni.
10
Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín, wọ́n fẹ́ kí á ko yín jìnnà sí ilẹ̀ yín ni. N óo le yín jáde; ẹ óo sì ṣègbé.
11
Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti ọrùn ara rẹ̀ bọ àjàgà ọba Babiloni, tí ó sì ń sìn ín, n óo fi sílẹ̀ lórí ilẹ̀ rẹ̀, kí ó lè máa ro ó, kí ó sì máa gbé ibẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
12
Iṣẹ́ yìí kan náà ni mo jẹ́ fún Sedekaya ọba Juda. Mo ní, “Fi ọrùn rẹ sinu àjàgà ọba Babiloni, kí o sin òun ati àwọn eniyan rẹ̀, kí o lè wà láàyè.
13
Kí ló dé tí ìwọ ati àwọn eniyan rẹ fẹ́ kú ikú idà, ikú ìyàn ati ikú àjàkálẹ̀ àrùn bí OLUWA ti wí pé yóo rí fún orílẹ̀-èdè tí ó bá kọ̀ tí kò bá sin ọba Babiloni?
14
Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń wí fun yín pé ẹ kò ní ṣe ẹrú ọba Babiloni, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín.
15
OLUWA ní òun kò rán wọn níṣẹ́. Wọ́n kàn ń fi orúkọ òun sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni, kí òun lè le yín jáde, kí ẹ sì ṣègbé, àtẹ̀yin àtàwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín.”
16
Lẹ́yìn náà, mo bá àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, mo ní, “OLUWA sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín tí wọn ń wí fun yín pé wọn kò ní pẹ́ kó àwọn ohun èlò ilé èmi OLUWA pada wá láti Babiloni. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín.
17
Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ sin ọba Babiloni, kí ẹ lè wà láàyè. Kí ló dé tí ìlú yìí yóo fi di ahoro?
18
Bí wọn bá jẹ́ wolii nítòótọ́, bí ó bá jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo fi ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu, ẹ ní kí wọn gbadura sí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, kí n má jẹ́ kí wọ́n kó àwọn ohun èlò tí ó kù ní ilé OLUWA ati ní ààfin ọba Juda ati ní Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.”
19
Àwọn ohun èlò kan ṣẹ́kù ninu ilé OLUWA, àwọn bíi: òpó ilé, ati agbada omi tí a fi idẹ ṣe, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó kù ninu ìlú yìí,
20
tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kò kó lọ, nígbà tí ó kó Jehoiakini, ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn ọlọ́lá Juda ati ti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.
21
OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Gbogbo àwọn ohun èlò tí ó ṣẹ́kù ní ilé rẹ, ati ní ààfin ọba Juda, ati ní Jerusalẹmu, ni
22
wọn óo kó lọ sí Babiloni, níbẹ̀ ni wọn yóo sì wà títí di ọjọ́ tí mo bá ranti wọn. N óo wá kó wọn pada wá sí ibí yìí nígbà náà.”
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52