bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Jeremiah 3
Jeremiah 3
Yoruba 2010
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 4 →
1
OLUWA ní, “Ṣé bí ọkọ bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀, tí iyawo náà sì kó jáde nílé ọkọ, tí ó lọ fẹ́ ẹlòmíràn, ṣé ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ lè tún lọ gbà á pada? Ṣé ilẹ̀ náà kò ní di ìbàjẹ́? Lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe àgbèrè pẹlu ọpọlọpọ olólùfẹ́; ẹ wá fẹ́ pada sọ́dọ̀ mi?
2
Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo gbogbo òkè yíká, ibo ni ẹ kò tíì ṣe àgbèrè dé? Ẹ̀ ń dúró de olólùfẹ́ lẹ́bàá ọ̀nà, bí àwọn obinrin Arabia ninu aṣálẹ̀. Ẹ ti fi ìṣekúṣe yín ba ilẹ̀ náà jẹ́.
3
Nítorí náà ni òjò kò ṣe rọ̀, tí òjò àkọ́rọ̀ kò rọ̀ ní àkókò tí ó yẹ. Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń gbéjú gbéré bí aṣẹ́wó, ojú kò sì tì yín.
4
Israẹli, o wá ń pè mí nisinsinyii, ò ń sọ pé, ‘Ìwọ ni baba mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.
5
Ṣé o kò ní dáwọ́ ibinu rẹ dúró ni? Tabi títí ayé ni o óo fi máa bínú?’ Lóòótọ́ o ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn o ti ṣe ìwọ̀n ibi tí o lè ṣe.”
6
OLUWA sọ fún mi ní ìgbà ayé ọba Josaya pé: “Ṣé o rí ohun tí Israẹli, alaiṣootọ ẹ̀dá ṣe? Ṣé o rí i bí ó tí ń lọ ṣe àgbèrè lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ gbogbo igi tútù?
7
Mo rò pé yóo pada tọ̀ mí wá, lẹ́yìn tí ó bá ṣe àgbèrè rẹ̀ tán ni; ṣugbọn kò pada; Juda arabinrin rẹ̀, alaiṣootọ sì rí i,
8
ó mọ̀ pé nítorí ìwà àgbèrè Israẹli, alaiṣootọ, ni mo ṣe lé e jáde, tí mo sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Sibẹsibẹ Juda tí òun pàápàá jẹ́ alaiṣootọ, kò bẹ̀rù, òun náà lọ ṣe àgbèrè.
9
Nítorí pé ìwà àgbèrè jẹ́ nǹkan kékeré lójú rẹ̀, ó ṣe àgbèrè pẹlu òkúta ati igi ó sì ba ilẹ̀ náà jẹ́.
10
Sibẹsibẹ, lẹ́yìn gbogbo èyí, Juda arabinrin rẹ̀, ọ̀dàlẹ̀, kò fi tọkàntọkàn pada tọ̀ mí wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú ayé ni wọ́n ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
11
Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún mi pé, “Israẹli jẹ̀bi, aiṣootọ, ṣugbọn kò tíì tó ti Juda, ọ̀dàlẹ̀.
12
Lọ kéde ọ̀rọ̀ yìí sí ìhà àríwá, kí o wí pé: ‘Yipada ìwọ Israẹli alaiṣootọ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní bínú sí ọ, nítorí aláàánú ni mí. N kò ní máa bínú lọ títí lae.
13
Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi, ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa, lábẹ́ gbogbo igi tútù; o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’
14
“Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni.
15
N óo fun yín ní àwọn olùṣọ́ aguntan tí ó wù mí, tí yóo fi ìmọ̀ ati òye bọ yín.
16
Nígbà tí ẹ bá pọ̀ síi ní ilẹ̀ náà, ẹ kò ní sọ̀rọ̀ nípa Àpótí Majẹmu OLUWA mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sọ si yín lọ́kàn, ẹ kò ní ranti rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín kò ní fà sí i mọ́, ẹ kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀
17
Ìtẹ́ OLUWA ni wọ́n óo máa pe Jerusalẹmu nígbà náà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ wá sibẹ, níwájú èmi OLUWA, ní Jerusalẹmu, wọn kò ní fi oríkunkun tẹ̀ sí ìmọ̀ burúkú ọkàn wọn mọ́.
18
Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ará ilé Juda yóo tọ àwọn ará ilé Israẹli lọ, wọn yóo sì jọ pada láti ilẹ̀ ìhà àríwá, wọn yóo wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n jogún.”
19
OLUWA ní, “Israẹli, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi, tí n óo sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó dára, kí n sì fún ọ ní ogún tí ó dára jù, láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù. Mo sì rò pé o óo máa pè mí ní baba rẹ, ati pé o kò ní pada kúrò lẹ́yìn mi.
20
Dájúdájú bí obinrin alaiṣootọ tíí fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o ti ṣe alaiṣootọ sí mi, ìwọ Israẹli. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
21
A gbọ́ ohùn kan lórí àwọn òkè gíga, ẹkún ati ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọkunrin Israẹli ni. Nítorí wọ́n ti yapa kúrò lójú ọ̀nà wọn; wọ́n ti gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn.
22
Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, n óo mú aiṣootọ yín kúrò. “Wò wá! A wá sọ́dọ̀ rẹ, nítorí ìwọ ni OLUWA Ọlọrun wa.
23
Nítòótọ́, ẹ̀tàn ni àwọn òkè, ati gbogbo ohun tí wọn ń lọ ṣe níbẹ̀; dájúdájú lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa ni ìgbàlà Israẹli wà.
24
Ṣugbọn láti ìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú yìí ti pa gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá wa ṣiṣẹ́ fún run: ẹran ọ̀sìn wọn, ati agbo mààlúù wọn, àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin.
25
Ẹ jẹ́ kí á dojúbolẹ̀ kí ìtìjú wa sì bò wá, nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wa; àtàwa, àtàwọn baba ńlá wa, a kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní.”
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52