bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Jeremiah 34
Jeremiah 34
Yoruba 2010
← Chapter 33
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 35 →
1
Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya sọ nìyí, nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati gbogbo ìjọba ayé tí wọ́n wà lábẹ́ rẹ̀, ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbógun ti Jerusalẹmu ati gbogbo àwọn ìlú Juda.
2
OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, kí n lọ sọ fún Sedekaya, ọba Juda pé òun OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ìlú yìí lé ọba Babiloni lọ́wọ́; yóo sì dáná sun ún.
3
Sedekaya, o kò ní sá àsálà, ṣugbọn wọn óo mú ọ, wọn óo fà ọ́ lé Nebukadinesari lọ́wọ́, ẹ óo rí ara yín lojukooju, ẹ óo bá ara yín sọ̀rọ̀, o óo sì lọ sí Babiloni.
4
Sibẹsibẹ, ìwọ Sedekaya, ọba Juda OLUWA ní wọn kò ní fi idà pa ọ́.
5
O óo fi ọwọ́ rọrí kú ni. Bí wọn ti sun turari níbi òkú àwọn baba rẹ, ati níbi òkú àwọn ọba tí wọ́n ti kú ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo sun turari níbi òkú ìwọ náà. Wọn yóo dárò rẹ, wọn yóo máa wí pé, ‘Ó ṣe, oluwa mi,’ nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA ṣe ìlérí; èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
6
Jeremaya wolii bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún Sedekaya ọba Juda, ní Jerusalẹmu,
7
ní àkókò tí àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu ati Lakiṣi ati Aseka, nítorí pé àwọn nìkan ni wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn ìlú olódi Juda.
8
OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Sedekaya ọba ti bá gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu dá majẹmu pé kí wọn kéde ìdásílẹ̀,
9
kí olukuluku dá ẹrú rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, tí wọ́n jẹ́ Heberu sílẹ̀, kí wọn máa lọ ní òmìnira; kí ẹnikẹ́ni má sì fi Juu arakunrin rẹ̀ ṣe ẹrú mọ́.
10
Gbogbo àwọn ìjòyè ati àwọn ará ìlú tí wọ́n dá majẹmu yìí ni wọ́n gbọ́ràn, tí wọ́n sì dá àwọn ẹrú wọn lọkunrin ati lobinrin sílẹ̀; wọn kò sì fi wọ́n ṣe ẹrú mọ́.
11
Ṣugbọn nígbà tó yá, wọ́n yí ọ̀rọ̀ pada, wọ́n tún mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, wọ́n tún fi ipá sọ wọ́n di ẹrú.
12
OLUWA wá sọ fún Jeremaya pé,
13
“Èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli bá àwọn baba ńlá yín dá majẹmu nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò lóko ẹrú ní ilẹ̀ Ijipti, mo ní,
14
lẹ́yìn ọdún meje, kí olukuluku yín máa dá ọmọ Heberu tí ó bá fi owó rà lẹ́rú sílẹ̀, lẹ́yìn tí ó bá ti sin oluwa rẹ̀ fún ọdún mẹfa. Mo ní ẹ gbọdọ̀ dá ẹrú náà sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ ní òmìnira, ṣugbọn àwọn baba ńlá yín kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.
15
Láìpẹ́ yìí, ẹ ronupiwada, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi; ẹ kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn arakunrin yín. Ẹ dá majẹmu níwájú mi ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè.
16
Ṣugbọn ẹ tún yí ọ̀rọ̀ pada, ẹ ba orúkọ mi jẹ́ nípa pé olukuluku yín, ẹ tún mú ẹrukunrin ati ẹrubinrin tí ẹ dá sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn yín, ẹ sì tún sọ wọ́n di ẹrú pada.
17
Nítorí náà ẹ kò gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu pé kí olukuluku kéde òmìnira fún arakunrin rẹ̀ ati ọmọnikeji rẹ̀. Ẹ wò ó! N óo kéde òmìnira fun yín: òmìnira sí ọwọ́ ogun, àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo sì fi yín ṣe ẹrú fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.
18
Àwọn ọkunrin tí wọn bá rú òfin mi, tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà majẹmu tí wọn dá níwájú mi, n óo bẹ́ wọn bíi ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí wọn bẹ́ sí meji, tí wọ́n sì gba ààrin rẹ̀ kọjá.
19
Bí àwọn ìjòyè Juda ati àwọn ìjòyè Jerusalẹmu, àwọn ìwẹ̀fà, àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ṣe bẹ́ ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù sí meji, tí wọn sì gba ààrin rẹ̀ kọjá láti bá mi dá majẹmu, ni n óo ṣe bẹ́ àwọn náà.
20
N óo fà wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn; òkú wọn yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.
21
N óo fi Sedekaya, ọba Juda ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn. Wọn óo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Babiloni tí ó ti ṣígun kúrò lọ́dọ̀ wọn.
22
Ẹ wò ó, n óo pàṣẹ, n óo sì kó wọn pada sí ìlú yìí, wọn yóo gbógun tì í, wọn yóo gbà á; wọn yóo sì dáná sun ún. N óo sọ àwọn ìlú Juda di ahoro, kò ní sí eniyan tí yóo máa gbé inú wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
← Chapter 33
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 35 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52