bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Jeremiah 14
Jeremiah 14
Yoruba 2010
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 15 →
1
Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Jeremaya nípa ọ̀gbẹlẹ̀ nìyí:
2
“Juda ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ẹnubodè ìlú rẹ̀ wà ninu ìnira. Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń sọkún ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀, igbe àwọn ará Jerusalẹmu sì ta sókè.
3
Àwọn ọlọ́lá ní ìlú rán àwọn iranṣẹ wọn lọ pọn omi, àwọn iranṣẹ dé odò, wọn kò rí omi. Wọ́n gbé ìkòkò omi wọn pada lófìfo, ojú tì wọ́n, ìdààmú dé bá wọn, wọ́n káwọ́ lérí.
4
Nítorí ilẹ̀ tí ó gbẹ, nítorí òjò tí kò rọ̀ ní ilẹ̀ náà, ojú ti àwọn àgbẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí.
5
Àgbọ̀nrín inú igbó pàápàá já ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, nítorí kò sí koríko.
6
Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè, wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko. Ojú wọn rẹ̀wẹ̀sì, nítorí kò sí koríko.
7
Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa, sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá. Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ, a ti ṣẹ̀ ọ́.
8
Ìwọ ìrètí Israẹli, olùgbàlà rẹ̀ ní ìgbà ìṣòro. Kí ló dé tí o óo fi dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà? Àní, bí èrò ọ̀nà, tí ó yà láti sùn mọ́jú?
9
Kí ló dé tí o fi dàbí ẹni tí ìdààmú bá; bí alágbára tí kò lè gbani là? Bẹ́ẹ̀ ni o wà láàrin wa, OLUWA, a sì ń fi orúkọ rẹ pè wá, má fi wá sílẹ̀.’ ”
10
OLUWA sọ nípa àwọn eniyan náà pé, “Ó wù wọ́n láti máa ṣáko kiri, wọn kò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn; nítorí náà wọn kì í ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA, nisinsinyii OLUWA yóo ranti àìdára wọn, yóo sì jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
11
OLUWA sọ fún mi pé, “Má gbadura pé kí àwọn eniyan wọnyi wà ní alaafia.
12
Wọn ìbáà gbààwẹ̀, n kò ní gbọ́ igbe wọn. Wọn ìbáà rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ, n kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Idà, ati ebi, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ni n óo fi pa wọ́n run.”
13
Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, wò ó! Àwọn wolii ń sọ fún wọn pé, wọn kò ní fojú kan ogun, tabi ìyàn, ati pé, alaafia tòótọ́ ni o óo fún wọn ní ibí yìí.”
14
OLUWA bá sọ fún mi pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ni àwọn wolii ń sọ ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́, n kò fún wọn láṣẹ, n kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí; iṣẹ́ asán ni wọ́n ń wò. Ohun tí ó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ.
15
Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA sọ ni pé, àwọn wolii tí n kò rán níṣẹ́, tí wọn ń jíṣẹ́ orúkọ mi, tí wọn ní èmi sọ pé ogun ati ìyàn kò ní wọ ilẹ̀ yìí, ogun ati ìyàn ni yóo pa àwọn gan-an run.
16
Wọn óo gbé àwọn eniyan tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún sọ síta ní òkú ní ìgboro Jerusalẹmu, nígbà tí ìyàn ati ogun bá pa wọ́n tán. Kò ní sí ẹni tí yóo sin òkú wọn, ati ti àwọn iyawo wọn, ati ti àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin. N óo da ibi tí wọ́n ṣe lé wọn lórí.”
17
OLUWA wí fun mi pé, “Sọ fún wọn pé, ‘Kí omijé máa ṣàn lójú mi tọ̀sán-tòru, kí ó má dáwọ́ dúró, nítorí ọgbẹ́ ńlá tí a fi tagbára tagbára ṣá eniyan mi.
18
Bí mo bá jáde lọ sí ìgbèríko, àwọn tí wọ́n fi idà pa ni wọ́n kún bẹ̀! Bí mo bá sì wọ ààrin ìlú, àwọn tí ìyàn di àìsàn sí lára ni wọ́n kún bẹ̀. Nítorí àwọn wolii ati àwọn alufaa ń lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà, wọn kò sì mọ ohun tí wọn ń ṣe.’ ”
19
OLUWA, ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ patapata ni? Àbí Sioni ti di ohun ìríra lọ́kàn rẹ? Kí ló dé tí o fi lù wá, tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ tiwa kọjá ìwòsàn? À ń retí alaafia, ṣugbọn ire kankan kò dé. À ń retí àkókò ìwòsàn, ṣugbọn ìpayà ni a rí.
20
OLUWA, a mọ ìwà burúkú wa, ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.
21
Má ta wá nù nítorí orúkọ rẹ, má sì fi àbùkù kan ìtẹ́ rẹ tí ó lógo. Ranti majẹmu tí o bá wa dá, ranti, má sì ṣe dà á.
22
Ninu gbogbo àwọn ọlọrun èké tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn, ǹjẹ́ ọ̀kan wà tí ó lè mú kí òjò rọ̀? Àbí ojú ọ̀run ní ń fúnrarẹ̀ rọ ọ̀wààrà òjò? OLUWA Ọlọrun wa, ṣebí ìwọ ni? Ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé, nítorí ìwọ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 51
Chapter 52
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52