bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Revelation 11
Revelation 11
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 12 →
1
A sì fi ìféèfé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹ́ḿpílì Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀.
2
Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹ́ḿpìlì sílẹ̀, má si ṣe wọ̀n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjì lé lógójì.
3
Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ̀rìí mi méjèèje, wọn o sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fa ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta nínú aṣọ-ọ̀fọ̀.”
4
Wọ̀nyí ni igi olífì méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé.
5
Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lara, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀ta wọn run: bayìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run.
6
Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn: wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-àrùn kọlu ayé, nígbàkúgbà tí wọ́n bá fẹ́.
7
Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n.
8
Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sódómù àti Éjíbítì nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú.
9
Fún ijọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì.
10
Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró,
11
Àti lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí iyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹṣẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn.
12
Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkúukúù àwọsánmà; lójú àwọn ọ̀ta wọn.
13
Ní wákàtí náà ìmìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ̀wàá ìlú náà sì wó, àti nínú ìmìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.
14
Ègbé kéjì kọjá; sì kìyèsí i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán.
15
Ańgẹ́lì kéje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, “Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kírísítì rẹ̀; òun yóò sì jọba láé àti láéláé!”
16
Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run,
17
Wí pé: “Àwa fí ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè, tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀, ìwọ sì ti jọba.
18
Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ni ìbínú rẹ̀ ti dé, àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́, àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì, àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀, àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá; àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”
19
A sì ṣí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mu nínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ́ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 12 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22