bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Revelation 15
Revelation 15
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 16 →
1
Mo sì rí àmì mìíràn ní ọ̀run tí ó tóbi tí ó sì ya ni lẹ́nu, àwọn ańgẹ́lì méje tí ó ni àwọn ìyọnu méje ìkẹ́yìn, nítorí nínú wọn ni ìbínú Ọlọ́run dé òpin.
2
Mo sì rí bí ẹni pé, òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n sẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti àmì rẹ̀ àti nọ́ḿba orúkọ rẹ̀, wọn ní Haàpù Ọlọ́run.
3
Wọ́n sì ń kọ orin ti Móṣè, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé: “Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Olúwa Ọlọ́run Olodùmarè; òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀, ìwọ Ọba àwọn orílẹ̀-èdè.
4
Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa, tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀? Nítorí ìwọ níkanṣoṣo ni mímọ́. Gbogbo àwọn orílẹ èdè mi yóò sì wá, ti yóò sì foribalẹ̀ níwájú rẹ, nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”
5
Lẹ́yìn náà mo sì wo, sì kíyèsí i, a sí tẹ́ḿpìlì àgọ́ ẹ̀rí ní ọ̀run sílẹ̀;
6
Àwọn ańgẹ́lì méje náà sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde wá, wọ́n ni ìyọnu méje náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun ti ń dán, a sì fi àmùrè wúrà dì wọ́n ni oókan àyà.
7
Àti ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fi àgbàda wúrà méje fún àwọn ańgẹ́lì méje náà, tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé.
8
Tẹ́ḿpìlì náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá; ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹ́ḿpìlì náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn ańgẹ́lì méje náà ṣẹ.
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22