bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Revelation 16
Revelation 16
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 17 →
1
Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti inú tẹ́ḿpìlì wá, ń wí fún àwọn ańgẹ́lì, méje nì pé, “Ẹ lọ, ẹ sì tú ìgò ìbínú Ọlọ́run wọ̀nnì sí orí ayé.”
2
Èkínní sì lọ, ó sì tú ìgò tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé: egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní àmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀.
3
Èkejì sì tú ìgò sínú òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn: gbogbo ọkàn alàyè sì kú nínú òkun.
4
Ẹ̀kẹ́ta sì tú ìgò tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.
5
Mo sì gbọ́ ańgẹ́lì ti omi wí pé: “Olódodo ni ìwọ Ẹni Mímọ́ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ báyìí.
6
Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀, ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.”
7
Mo sì gbọ́ pẹpẹ ń ké wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.”
8
Ẹ̀kẹrin sì tú ìgò tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára.
9
A sì fi oru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.
10
Ẹ̀karùn-ún sì tú ìgo tirẹ̀ sórí ìtẹ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì sókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora.
11
Wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronupìwàdà iṣẹ́ wọn.
12
Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Yúfúrátè; omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèṣè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà òòrùn wá.
13
Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dírágónì náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá.
14
Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olúdàmarè.
15
“Kíyèsí i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń sọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó mà bàá rìn ni ìhóhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”
16
Ó sì gbá wọn jọ́ sí ìbikan tí a ń pè ní Ámágédónì ní èdè Hébérù.
17
Èkeje si tú ìgo tírẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹ́ḿpìlì jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!”
18
Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò sẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tóbẹ́ẹ̀.
19
Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Bábílónì ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un.
20
Olúkúlùkù erekúṣu sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́.
21
Yìnyín ńlá, tí ọkọkan rẹ̀ tó talẹ́ntì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà: Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà; nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22