bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Revelation 13
Revelation 13
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 14 →
1
Mo sì rí ẹranko kan ń ti inú òkun jáde wá, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, lórí àwọn ìwo náà ni orúkọ ọ̀rọ̀-òdì wà.
2
Ẹranko tí mo rí náà sì dàbí ẹkùn, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí tí béárì ẹnu rẹ̀ sì dàbí tí kìnnìún: dírágónì náà sì fún un ni agbára rẹ̀, àti ìtẹ́ rẹ̀, àti àṣẹ ńlá.
3
Mo sì rí ọ̀kan nínú àwọn orí rẹ̀ bí ẹni pé a ṣá a pa, a sì tí wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ náà sàn, gbogbo ayé sì fi ìyanu tẹ̀lé ẹranko náà.
4
Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún dírágónì náà, nítorí tí o fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, wí pé, “Ta ni o dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó sì lè bá a jagun?”
5
A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀ òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì.
6
Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run.
7
A sì fún-un láti máa bá àwọn ènìyàn-mímọ́ jagun, àti láti ṣẹ́gun wọn: a sì fi agbára fún un lórí gbogbo ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, àti orílẹ̀.
8
Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlúkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé-ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.
9
Bí ẹnikẹ́ni bá létí kí o gbọ́.
10
Ẹni tí a ti pinnu rẹ̀ fún ìgbékùn, ìgbékùn ni yóò lọ; ẹni tí a sì ti pinnu rẹ̀ fún idà, ni a ó sì fi idà pa. Nihìn-ín ni sùúrù àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà.
11
Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí Ọ̀dọ́-Àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dírágónì.
12
Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn.
13
Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn.
14
Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fí fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè.
15
A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà.
16
Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti talákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba àmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn;
17
Àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní àmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí àmì orúkọ rẹ̀
18
Niyìn ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka nọ́ḿbà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà: nítorí pé nọ́ḿbà ènìyàn ni, nọ́ḿbà rẹ̀ náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta ọgọ́ta ẹẹ́fà. (666).
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22