bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Revelation 8
Revelation 8
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 9 →
1
Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kéje, ìdákẹ́ rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ́n ààbọ̀ wákàtí kan.
2
Mo sì rí àwọn ańgẹ́lì méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn.
3
Ańgẹ́lì mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fí kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́.
4
Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn-mímọ́ sì gòkè lọ ṣíwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ ańgẹ́lì náà wá.
5
Ańgẹ́lì náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé: A sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì.
6
Àwọn ańgẹ́lì méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.
7
Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀: Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ̀ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ̀ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jónà.
8
Ańgẹ́lì kéjì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òké-ńlá tí ń jóná, sínú òkun: ìdámẹ̀ta òkun si di ẹ̀jẹ̀;
9
Àti ìdámẹ̀ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ̀ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́.
10
Ańgẹ́lì kẹ́ta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ̀ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi;
11
A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ni ìwọ̀, ìdámẹ̀ta àwọn omi sì di ìwọ̀, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.
12
Ańgẹ́lì kẹ́rin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ̀ta òòrùn, àti ìdámẹ̀ta òṣùpá, àti ìdámẹ̀ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ̀ta wọn lè ṣóòkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ̀ta rẹ̀, àti òru báka náà.
13
Mo sì wò, mo sì gbọ́ idí kan tí ń fò ni àárin ọ̀run, ó ń wí lóhùn rara pé, “Ègbé, ègbé, fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé nítorí ohun ìpè ìyókù tí àwọn ańgẹ́lì mẹ́ta tí ń bọ̀ wá yóò fún!”
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22