bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Song of Solomon 1
Song of Solomon 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 2 →
1
Orin àwọn orin tí i ṣe orin Sólómónì
2
Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.
3
Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra. Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jáde Abájọ tí àwọn wúndíá fi fẹ́ ọ.
4
Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíá Ọba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀. Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ; a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ. Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!
5
Èmi dúdú mo sì ní ẹwà. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Dúdú bí àgọ́ Kédárì Bí àgọ́ aṣọ kọ́tìnnì ti Sólómónì
6
Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdú Nítorí òòrùn mú mi dúdú Ọmọkùnrin ìyá mi bínú sími Ó sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà. Ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú
7
Ṣọ fún mi ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, Níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ. Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán. Kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin aṣán Ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
8
Bí ìwọ kò bá mọ̀, Ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin. Bá ọ̀nà ti agbo ẹran rìn lọ. Kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ. Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùsọ́ àgùntàn.
9
Olùfẹ́ mi, Mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Fáráò.
10
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́, Ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀
11
A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ, A ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.
12
Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀. Òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.
13
Ìdì òjíá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi. Òun ó sinmi lé àárin ọmú mi.
14
Bí ìdì ìtàná Hénínà ni Olùfẹ́ mi rí sí mi Láti inú ọgbà àjàrà ti Énígédì.
15
Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olùfẹ́ mi! Áá à, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó! Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.
16
Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi! Áá à, Báwo ni o ṣe wu ni! Ibùsùn wa ní ìtura.
17
Ìtànsán ilé wa jẹ́ ti igi kédárì Ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi Fírì.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8