bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Song of Solomon 7
Song of Solomon 7
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 8 →
1
Báwo ni ẹṣẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà, Ìwọ ọmọbìnrin ọba! Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́ iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
2
Ìdodo rẹ rí bí àwo tí kì í ṣe aláìní ọtí, ìbàdí rẹ bí òkìtì àlìkámà tí a fi lílì yíká.
3
Ọmú rẹ rí bí abo àgbọ̀nrín méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
4
Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín-erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Héṣébónì ní ẹ̀bá ẹnu ìbodè Bátírábímù. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lẹ́bánónì tí ó kọ ojú sí Dámásíkù.
5
Bí òkè kámẹlì ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká Bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.
6
Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́!
7
Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ, àti ọmú rẹ bí idì èso àjàrà.
8
Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ; Èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú” Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà, Àti èémi imú rẹ bí i ápù.
9
Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ. Tí ó kúnná tí ó sì dùn, tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀
10
Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe, èmí sì ni ẹni tí ó wù ú.
11
Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá, Jẹ́ kí a lo àṣálẹ̀ ní àwọn ìletò
12
Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù láti wo bí àjàrà rúwé bí ìtànná àjàrà bá là. Àti bí póméegíránéètì bá ti rúdí, níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13
Àwọn èṣo mánídárákì mú òórùn wọn jáde ní ẹnu ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso, èso ọ̀tún àti àkúgbó tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8