bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Song of Solomon 2
Song of Solomon 2
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 3 →
1
Èmi ni ìtànná Ṣárónì Bí ìtàná lílì àwọn àfonífojì
2
Bí ìtànná lílì ní àárin ẹ̀gún ni olùfẹ́ mi ní àárin àwọn wúndíá.
3
Bí igi ápù láàrin àwọn igi inú igbó, ni olùfẹ́ mí láàrin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀, Èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.
4
Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àṣè, Ìfẹ́ sì ni ọ̀pàgun rẹ̀ lórí mi.
5
Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró. Fi èṣo ápù tù mi lára Nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
6
Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi Ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra
7
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú Kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè Kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú
8
Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀. Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kékèké
9
Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà
10
Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, “Dìde, Olùfẹ́ mi, Arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.
11
Wò ó! Ìgbà otútù ti kọjá; Òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.
12
Àwọn òdòdó fara hàn lórí ilẹ̀ Àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé A sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13
Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde Àwọn àjàrà nípa ìtànná wọn fún ni ní òórùn dídùn Dìde, wá, Olùfẹ́ mi; Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”
14
Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ; Nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà.
15
Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kékèké tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtàná.
16
Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀; Ó ń jẹ láàrin àwọn lílì.
17
Títí ìgbà ìtura ọjọ́ títí òjìji yóò fi fò lọ, yípadà, olùfẹ́ mi, kí o sì dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín lórí òkè Bétérì.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8