bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Song of Solomon 6
Song of Solomon 6
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 7 →
1
Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ, Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin? Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí, kí a lè bá ọ wá a?
2
Olùfẹ́ mi ti ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀, sí ibi ibùsùn tùràrí, láti máa jẹ nínú ọgbà láti kó ìtànná lílì jọ.
3
Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi, Ó ń jẹ láàárin ìtànná lílì,
4
Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tírísà, Ìwọ lẹ́wà bí i Jérúsálẹ́mù, ìwọ lẹ́rù bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.
5
Yí ojú rẹ kúrò lára mi; nítorí ojú rẹ borí mi. Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́ tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gílíádì.
6
Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn, Tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá, gbogbo wọn bí ìbejì, kò sì sí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.
7
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bá ìbòjú rẹ, rí bí ẹ̀là èso pómégíránéètì.
8
Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀, àti ọgọ́rin àlè, àti àwọn wúndíá láìníye.
9
Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni, ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ, ààyò ẹyọkan ṣoṣo ẹni tí ó bí i. Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún Àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fun-un
10
Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí òòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?
11
Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì, láti rí i bí àjàrà rúwé, tàbí bí pómégíránéètì ti rúdìí.
12
Kí èmi tó mọ̀, àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàárin àwọn ènìyàn mi.
13
Padà wá, padà wá, ìwọ Ṣúlámátì: padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣúlámátì wò, bí ẹni pé orin ijo Máhánáímù?
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8