bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Song of Solomon 5
Song of Solomon 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 6 →
1
Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; mo ti kó òjíá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ. Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi; mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi. Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu, àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́
2
Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí. Gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ilẹ̀kùn. “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi Orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru.”
3
Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀? Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?
4
Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ilẹ̀kùn inú mi sì yọ́ sí i
5
Èmi dìde láti sílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, òjíá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi, òjíá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń ṣàn sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn
6
Èmi sí ilẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀. Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i. Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn
7
Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká. Wọ́n nà mí, wọ́n ṣá mi lọ́gbẹ́; wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!
8
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo bẹ̀ yín bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi, kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un? Ẹ wí fún un pé àìṣàn ìfẹ́ ń ṣe mi.
9
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọ Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọ tí ìwọ fi ń rọ̀ wá bẹ́ẹ̀?
10
Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ.
11
Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ ìdì ìrun rẹ̀ rí bí i ìmọ̀ ọ̀pẹ ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò
12
Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà ní ẹ̀bá odò tí ń ṣàn, tí a fi wàrà wẹ̀, tí ó jìn, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́
13
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí ti ó sun òórùn tùràrí dídùn Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì ó ń kán òjíá olóòórùn dídùn
14
Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà, tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán tí a fi Ṣáfírè ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
15
Ẹṣẹ̀ rẹ̀ rí bi i òpó mábù tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kédárì Lẹ́bánónì, tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.
16
Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ ó wu ni pátapáta. Áà! Ẹ̀yín ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, Èyí ní olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8