bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Genesis 14
Genesis 14
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 15 →
1
Ní àsìkò yìí ni Ámúráfélì ọba Ṣínárì, Áríókù ọba Élásárì, Kédóláómérì ọba Élámù àti Tídálì ọba Góímù
2
jáde lọ láti bá Bérà ọba Ṣódómù, Bírísà ọba Gòmórà, Ṣínábù ọba Ádímà, Ṣémébérì ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà (èyí-ni nì Ṣóárì) jagun.
3
Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí àfonífojì Ṣídímù (òkun iyọ̀).
4
Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kédóláómérì bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i.
5
Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kédóláómérì àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n sígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ara Ráfáímù ní Aṣilerótì-Kánáímù, àwọn ará Ṣúsítù ni Ámù, àwọn ará Émímù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriátaímù,
6
àti àwọn ará Hórì ní orí-òkè wọ̀nnì Ṣéírì, títí ó fi dé Eli-Páránì ní etí ijù.
7
Wọ́n sì tún yípadà lọ sí Ẹn-Mísífátì (èyí yìí ni Kádésì), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámálékì, àti àwọn ará Ámórì tí ó tẹ̀dó sí Haṣaṣoní Támárì pẹ̀lú.
8
Nígbà náà ni ọba Ṣódómù, ọba Gòmórà, ọba Ádímà, ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà (èyí ni Ṣóárì), kó àwọn ọmọ ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó-ogun wọn sí àfonífojì Ṣídímù,
9
láti kojú ìjà sí Kedolaómérì ọba Élámù, Tídà ọba Góímù, Ámúráfélì ọba Ṣínárì àti Áríókì ọba Élásà (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún).
10
Àfonífojì Ṣídímù sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Ṣódómù àti ọba Gòmórà sì ṣá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà subú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè.
11
Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Ṣódómù àti Gòmórà àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ.
12
Wọ́n sì mú Lọ́tì ọmọ arákùnrin Ábúrámù tí ń gbé ní Ṣódómù àti gbogbo ohun-ìní rẹ̀.
13
Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Ábúrámù, ará Ébérù. Ábúrámù sá ti tẹ̀dó sí igbó igi Óákù tí ó jẹ́ ti Mámúrè ará Ámórì, arákùnrin Ésíkólì àti Ánérì: àwọn ẹni tí ó ń bá Ábúrámù ní àṣepọ̀.
14
Nígbà tí Ábúrámù gbọ́ wí pé, a di Lọ́tì ní ìgbékùn, o kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ́ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dánì.
15
Ní ọ̀gànjọ́ òru, Ábúrámù pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Oba, ní àríwá Dámásíkù.
16
Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọ́tì pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó kù.
17
Nígbà tí Ábúrámù ti ṣẹ́gun Kedolaómérì àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Ṣódómù lọ pàdé e rẹ̀ ní àfonífojì Ṣáfè (èyí tí ó túmọ̀ sí Àfonífojì ọba).
18
Mélíkísédékì ọba Ṣálẹ́mù (Jérúsálẹ́mù) sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run, ọ̀gá ògo.
19
Ó sì súre fún Ábúrámù wí pé, “Ìbùkún ni fún Ábúrámù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ọ̀gá ògo tí ó dá ọ̀run òun ayé.
20
Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run ọ̀gá ògo jùlọ tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.” Ábúrámù sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.
21
Ọba Ṣódómù sì wí fún Ábúrámù pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”
22
Ṣùgbọ́n Ábúrámù dá ọba Ṣódómù lóhùn pé, “Mo ti búra fún OLÚWA, Ọlọ́run ọ̀gá ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè,
23
pé, èmi kì yóò mú ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ se tèmi, ìbáà kéré bí orí abẹ́rẹ́, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’
24
Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Ánérì, Ésíkólì àti Mámúrè. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.”
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50