bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Genesis 9
Genesis 9
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 10 →
1
Ọlọ́run sì súre fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ wí pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì pọ̀ ní iye, kí ẹ sì kún aye.
2
Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.
3
Gbogbo ohun tó wà láàyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún-ún yín bí mo ṣe fi ewéko fún un yín, náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.
4
“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
5
A ó jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ta ẹ̀jẹ̀ (gba ẹ̀mí) ènìyàn sílẹ̀ níyà. Ikú ni yóò jẹ́ ìjìyà ìpànìyàn, ìbá à ṣe láti ọwọ́ ẹranko tàbí ènìyàn.
6
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni Ọlọ́run dá ènìyàn.
7
Ṣùgbọ́n ní tiyín, ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ máa gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀, kí ẹ sì pọ̀ sí i lórí rẹ̀.”
8
Ọlọ́run sì wí fún Nóà àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé:
9
“Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn.
10
Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbáà ṣe ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé.
11
Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.”
12
Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀:
13
Mo ti fi òṣùmàrè sí ojú ọ̀run, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrin èmi àti ayé.
14
Nígbàkúgbà tí mo bá mú kí òjò sú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní ojú ọ̀run.
15
Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrin èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run.
16
Nígbàkígbà tí òsùmàrè bá yọ ní ojú ọ̀run, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrin Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”
17
Ọlọ́run sì wí fún Nóà pé, “Èyí ni àmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrin èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.”
18
Àwọn ọmọ Nóà tí ó jáde nínú ọkọ̀ ni Ṣémù, Ámù àti Jáfétì. (Ámù ni bàba Kénánì).
19
Nípaṣẹ̀ àwọn ọmọ Nóà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni gbogbo ènìyàn ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé.
20
Nóà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà.
21
Ó mu àmupara nínú ọtí wáìnì àjàrà rẹ̀, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò, ó sì sùn nínú àgọ́ rẹ̀.
22
Ámù tí í ṣe baba Kénání sì rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ méjèèjì ní ìta.
23
Ṣùgbọ́n Ṣémù àti Jáfétì mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòòhò baba wọn. Wọ́n kọjú ṣẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòòhò baba wọn.
24
Nígbà tí ọtí dá kúrò ní ojú Nóà, tí ó sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ àti ohun tí Ámù ọmọ rẹ̀ ṣe sí i.
25
Ó wí pé: “Ègún ni fún Kénánì. Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máa ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”
26
Ó sì tún wí pé; “Olùbùkún ni OLÚWA, Ọlọ́run Ṣémù Kénánì yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣémù.
27
Ọlọ́run yóò mú Jáfétì gbilẹ̀, Jáfétì yóò máa gbé ní àgọ́ Ṣémù Kénánì yóò sì jẹ́ ẹrú fún-un.”
28
Nóà wà láàyè fún irínwó-ọdún-ó-dín-àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi.
29
Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Nóà jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-ní-àádọ́ta ọdún, (950) ó sì kú.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50