bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Genesis 3
Genesis 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 4 →
1
Ejò ṣáà ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yóòkù tí OLÚWA Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ há ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èṣo èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”
2
Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, “Àwá lè jẹ lára àwọn èṣo igi tí ó wà nínú ọgbà,
3
ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èṣo igi tí ó wà láàrin ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kú.’ ”
4
Ejò wí fún obìnrin náà pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.”
5
“Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú.”
6
Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èṣo igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.
7
Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn.
8
Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró OLÚWA Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú OLÚWA Ọlọ́run sí àárin àwọn igi inú ọgbà.
9
Ṣùgbọ́n OLÚWA Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”
10
Ó dáhùn pé, “Mo gbúrò ó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí nítorí pé, mo wà ní ìhòòhò, mo sì fi ara pamọ́.”
11
Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”
12
Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èṣo igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”
13
Nígbà náà ni OLÚWA Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”
14
Nígbà náà ni OLÚWA Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹran igbó tó kù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
15
Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárin ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”
16
Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé: “Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ; ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ. Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”
17
Ọlọ́rún sì wí fún Ádámù pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
18
Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èsùsú fún ọ, ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.
19
Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ ṣáà ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”
20
Ádámù sì sọ aya rẹ̀ ní Éfà nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè.
21
OLÚWA sì dá ẹ̀wù awọ fún Ádámù àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.
22
OLÚWA Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èṣo igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láàyè títí láéláé.”
23
Nítorí náà, OLÚWA Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá.
24
Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tan, ó fi àwọn Kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ̀nà ṣíwájú àti sẹ́yìn, sọ́ ọ̀nà tí ó lọ síbi igi ìyè, ní ìhà ìlà oòrún ọgbà Édẹ́nì.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50