bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Genesis 39
Genesis 39
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 38
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 40 →
1
Nígbà tí wọ́n mú Jósẹ́fù dé Éjíbítì, Pótífà, ará Éjíbítì tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Fáráò. Òun ni olórí àwọn ọmọ ogun Fáráò. Ó ra Jósẹ́fù lọ́wọ́ àwọn ará Íṣímáẹ́lì tí wọ́n mú-un lọ ṣíbẹ̀.
2
OLÚWA sì wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì bùkún-un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Éjíbítì.
3
Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé OLÚWA wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé OLÚWA jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé.
4
Jósẹ́fù sì rí ojúrere Pọ́tífà, ó sì di asojú rẹ̀, Pọ́tífà fi Jósẹ́fù ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.
5
Láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun-ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún-un nítorí Jósẹ́fù. Ìbùkún OLÚWA wà lórí gbogbo ohun tí Pọ́tífà ní, nílé àti lóko.
6
Ó sì fi Jósẹ́fù ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Jósẹ́fù ṣe àkóṣo ilé e rẹ̀. Josẹ́fù sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀,
7
lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Jósẹ́fù, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lò pọ̀!”
8
Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, OLÚWA mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́.
9
Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?”
10
Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Jósẹ́fù, Jósẹ́fù kọ̀ láti bá a lò pọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.
11
Ní ọjọ́ kan, Jósẹ́fù lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí.
12
Ó sì di aṣọ Jósẹ́fù mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lò pọ̀!” Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde.
13
Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde,
14
ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Ébérù kan wọlé tọ̀ wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lò pọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe.
15
Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sokè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.”
16
Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé.
17
Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará a Ébérù tí o rà wálé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lò pọ̀.
18
Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.”
19
Nígbà tí Pọ́tífà gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi.
20
Ó sì ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jóṣẹ́fù wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀,
21
OLÚWA sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì sàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà).
22
Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Jọ́ṣẹfù ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń se níbẹ̀.
23
Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Jósẹ́fù, nítorí pé OLÚWA wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ lé.
← Chapter 38
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 40 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50