bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Genesis 35
Genesis 35
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 34
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 36 →
1
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jákọ́bù pé, “Gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì kí o sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀, kí o mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sá lọ kúrò níwájú Íṣọ̀ arákùnrin rẹ.”
2
Nítorí náà, Jákọ́bù wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjòjì òrìsà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín.
3
Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Bẹ́tẹ́lì, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.”
4
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jákọ́bù ní gbogbo àjòjì òrìsà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jákọ́bù sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sabẹ́ igi Óákù ní Ṣékémù.
5
Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn. Ìbẹ̀rù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì ń bá lé gbogbo ìlú tí wọ́n ń là kọjá ní ọ̀nà wọn tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹni tí ó le è dojú ìjà kọ wọ́n.
6
Jákọ́bù àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lúsì (Bẹ́tẹ́lì) tí ó wà ní ilẹ̀ Kénánì.
7
Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Bẹ́tẹ́lì (Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì), nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn-án nígbà tí ó ń sá lọ fún arákùnrin rẹ̀.
8
Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Dèbórà, olùtọ́jú Rèbékà kú, a sì sin-ín sábẹ́ igi Óàkù ní ìsàlẹ̀ Bẹ́tẹ́lì: Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bákútì (Óákù Ẹkún).
9
Lẹ́yìn tí Jákọ́bù padà dé láti Padani-Árámù, Ọlọ́run tún fara hàn-án, ó sì súre fún un.
10
Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jákọ́bù ni orúkọ rẹ̀, a kì yóò pè ọ́ ní Jákọ́bù (alọ́nilọ́wọ́gbà) mọ́ bí kò ṣe Ísírẹ́lì (ẹni tí ó bá Ọlọ́run jìjàkadì, tí ó sì ṣẹ́gun).” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.
11
Ọlọ́run sì wí fún-un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára; máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀.
12
Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Ábúráhámù àti Ísáákì ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.”
13
Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀.
14
Jákọ́bù sì fi òkúta ṣe òpó kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ó sì ta ọrẹ ohun mímu (wáìnì) ní orí rẹ̀, ó sì da òróró ólífì sí orí rẹ̀ pẹ̀lú.
15
Jákọ́bù sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.
16
Nígbà náà ni wọ́n ń tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò wọn láti Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tí ó sì ku díẹ̀ kí wọn dé Éfúrátì, Rákélì bẹ̀rẹ̀ sí ní rọbí, ó sì ní ìdààmú púpọ̀.
17
Bí ó sì ti ń rọbí pẹ̀lú ìrora yìí, agbẹ̀bí wí fún-un pé “Má bẹ̀rù nítorí ọmọkùnrin mìíràn ni ó ń bọ̀ yìí.”
18
Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi (torí pé ó ń kú lọ), ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bẹni-Ónì (ọmọ ìpọ́njú mi). Ṣùgbọ́n Jákọ́bù sọ ọmọ náà ní Bẹ́ńjámínì (ọmọ oókan àyà mi).
19
Báyìí ni Rákélì kú, a sì sin-ín sí ọ̀nà Éfúrátì (Bẹ́tílẹ́hẹ́mù).
20
Jákọ́bù sì mọ òpó (ọ̀wọ̀n) kan sí ibojì rẹ̀, òpó náà sì tọ́ka sí ojú ibojì Rákélì títí di òní.
21
Ísírẹ́lì sì ń bá ìrìn-àjò rẹ̀ lọ, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí Migida-Édérì (ilé-ìsọ́ Édérì).
22
Nígbà tí Ísírẹ́lì sì ń gbé ní ibẹ̀, Rúbẹ́nì wọlé tọ Bílíhà, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, Ísírẹ́lì sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Jákọ́bù sì bí ọmọkunrin méjìlá:
23
Àwọn ọmọ Líà: Rúbẹ́nì tí í ṣe àkọ́bí Jákọ́bù, Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì àti Ṣébúlúnì.
24
Àwọn ọmọ Rákélì: Jóṣẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.
25
Àwọn ọmọ Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin Rákélì: Dánì àti Náfítalì.
26
Àwọn ọmọ Ṣílípà ìránṣẹ́-bìnrin Líà: Gádì àti Áṣérì. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jákọ́bù bí ní Padani-Árámù.
27
Jákọ́bù sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni Mámúrè ní tòsí i Kiriati-Árábà (Hébúrónì). Níbi tí Ábúráhámù àti Ísáákì gbé.
28
Ẹni ọgọ́sán-an (180) ọdún ni Ísáákì.
29
Ísáákì sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jákọ́bù, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́-ogbó rẹ̀. Ísọ̀ àti Jákọ́bù ọmọ rẹ̀ sì sin-ín.
← Chapter 34
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 36 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50