bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Genesis 15
Genesis 15
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 16 →
1
Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Ábúrámù wá lójú ìran pé: Ábúrámù má ṣe bẹ̀rù, Èmi ni ààbò rẹ, Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.
2
Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, “OLÚWA, alágbára, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Élíásérì ará Dámásíkù ni yóò sì jogún mi,”
3
Ábúrámù sì tún tẹ̀ṣíwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé è mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”
4
Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tún tọ̀ ọ́ wá pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé (ajogún) rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnrarẹ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.”
5
OLÚWA sì mú Ábúrámù jáde síta ó sì wí fún un pé, “Gbójú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀-bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú ọmọ rẹ yóò rí.”
6
Ábúrámù sì gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sì òdodo fun-un.
7
Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni OLÚWA tí ó mú ọ jáde láti Úrì ti Kálídéà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”
8
Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, “OLÚWA Ọlọ́run, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”
9
Nítorí náà, OLÚWA wí fún-un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́tamẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”
10
Ábúrámù sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjìméjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣugbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn.
11
Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Ábúrámù sì ń lé wọn.
12
Bí oòrùn ti ń wọ̀, Ábúrámù sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó.
13
Nígbà náà ni OLÚWA wí fún un pé, “Mọ èyí dájú pé, àwọn ìran rẹ yóò ṣe àtìpó ní orílẹ̀ èdè tí kì í ṣe ti wọn, a ó kó wọn lẹ́rú, a ó sì jẹ wọ́n ní ìyà fún irínwó ọdún (400).
14
Ṣùgbọ́n èmi yóò dá orílẹ̀ èdè náà tí wọn yóò sìn lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀.
15
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin.
16
Ní ìran kẹ́rin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Ámórì kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n.”
17
Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì sú, ìkòkò iná tí ń sèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrin ẹ̀là a ẹran náà.
18
Ní ọjọ́ náà gan-an ni OLÚWA dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ábúrámù, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Éjíbítì dé odò ńlá Yúfúrátè:
19
ilẹ̀ àwọn ará Kénì, Kádímónì,
20
Ítì, Pérísísì, Réfáímù.
21
Ámórì, Kénánì, Gírígásì àti Jébúsì.”
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50